Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 12

Ṣe àpèjúwe ojúṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí nínú ètò agbo-ilé

 

Observation

Candidates were required to explain the roles of the family head, the oldest wife and the male children in Yoruba traditional family setting.

 

(a) Ojúṣe Baálé:
i.          píparí ìjà láàrín àwọn ọmọ-ilé
ii.         àlejò gbígbà sí agbo-ilé
iii.        lílé àlejò búburú kúrò nínú agbo-ilé
iv.        ṣíṣe àbójútó ìfiọmọlọ́kọ/ìfẹ́bìnrinfọ́mọ
v.         ṣíṣe ìtọ́jú aboyún ilé
vi.        ṣíṣe ètò ìsọmọlórúkọ/ìkómọjáde
vii.       gbígba owó-orí àwọn ọmọkùnrin ilé jọ
viii.      mímójútó orò ilé
ix.        mímójútó ètò ìsìnkú
x.         ṣíṣe agbẹnusọ fún agbo-ilé nínú ìpàdé ìlú/àdúgbò
xi.        mímójútó ètò oyè jíjẹ tí ó kan agbo-ilé

(b)        Ojúṣe Ìyáalé:
i.          bíbá baálé ilé dámọ̀ràn
ii.         ṣíṣe àlàyé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ọjọ́-orí àwọn ọmọ ilé
iii.        ṣíṣe àkóso àwọn obìnrin-ilé/ìyàwó-ilé
iv.        ṣíṣe ìtọ́jú ìyàwó tuntun
v.         ṣíṣe àkóso àwọn obìnrin níbi ayẹyẹ/ìnáwó/ọdún/orò ilé
vi.        ṣíṣe ìtọ́jú aboyún àti ọmọ wẹ́wẹ́ ní agbo-ilé
vii.       píparí ìjà láàrin àwọn obìnrin-ilé/ìyàwó-ilé
viii.      píparí ìjà láàrin àwọn ọmọ-ilé lóbìnrin
ix.        mímójútó ìmọ́tótó agbo-ilé
x.         ṣíṣe ètò ìgbàlejò ní agbo-ilé

(d)       Ojúṣe Ọmọkùnrin-ilé:
i.          ríran àwọn àgbà ilé lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó gba agbára bíi igi lílà, títún ilé kọ́, abbl
ii.         ríro àyíka agbo-ilé
iii.        ṣíṣe aṣojú agbo-ilé nínú iṣẹ́ ogun jíjà
iv.        pípa koríko bẹẹrẹ/ewé/imọ̀ fún ìlò ilé tàbí ìlú
v.         gbígbẹ́ ilẹ̀ láti sin ibi ọmo, òkú àbíkú, abbl
vi.        pípa ẹran níbi ìnáwó agbo-ilé
vii.       ríran àwọn àgbà ilé lọ́wọ́ níbi àṣeyẹ/ìnáwó agbo-ilé
viii.      ṣíṣe aṣojú agbo-ilé nínú iṣẹ́ ìlú bíi ọ̀nà yíyẹ̀, odò gbígbẹ́, ìdáàbòbò ìlú,         títún ààfin kọ́, abbl
ix.        kíkópa nínú ọ̀wẹ̀ tí ó pa ọmọ-ilé pọ̀

Most of the candidates who attempted this question performed fairly well.