Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 12

    Báwo ni àwọn Yorùbá ṣe ń lo àrokodóko láti fi ran ara wọn lọ́wọ́ ní ìgbà àtijọ́


Observation

Candidates were expected to discuss how the ancient custom of cooperative crop farming was being used to help one another in the olden days in Yoruba tradition.

Bí àwọn Yorùbá ṣe ń lo àrokodóko láti fi ran ara wọn lọ́wọ́ ní ìgbà àtijọ́:

  1. Àwọn àgbẹ̀ tí oko wọn sún mọ́ ara wọn ni wọ́n máa ń lo  irúfẹ́ àáró yìí láì gba owó iṣẹ́
  2. Àwọn àgbẹ̀ tí ó jẹ́ irọ̀ tí wọ́n sì lágbára bákan náà ni ó máa ń wà nínú ẹgbẹ́ àrokodóko
  3. Wọ́n á ṣètò bí wọn yóò ṣe máa ṣe iṣẹ́ oko yìí ní àárín ara wọn       
  4. Tí wọn bá ṣiṣẹ́ lóko ẹni kan tán, wọ́n á lọ sí oko ẹlòmíràn
  5. Ẹni tí iṣẹ́ bá kàn lè pèsè jíjẹ àti mímu
  6. Wọ́n máa ń ṣe àdéhùn láti ṣe ìwọ̀n iṣẹ́ kan náà nínú oko ẹnì kọ̀ọ̀kan kí      ó má baà sí ìrẹ́jẹ
  7.  Ó máa ń mú ìrẹ́pọ̀ wà láàrin àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ìranra-ẹni-lọ́wọ́ yìí
  8. Kò fi àyè gba ìmẹ́lẹ́ rárá
  9.  Ó máa ń jẹ́ kí oko àgbẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ̀
  10.  Ó máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ yá

Some of the candidates who attempted this question did justice to it. However, some candidates mistook it for the paid farming system.