Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 4   

 

(a)     Ṣe àtúnpín àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí sí abẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe ẹlẹ́là àti aláìlẹ́là:
(i)         dìde
(ii)        bẹ̀wò
(iii)       pàdé
(iv)       ṣubú
(v)        gbàgbọ́
(vi)       rẹ́jẹ
(vii)      tànjẹ
(viii)     sáré
(ix)       bẹ̀rẹ̀
(x)        báwí

(b)   Lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó wà ní 4(a) nínú gbólóhùn

Observation

Candidates were required to classify the given verbs into splitting and non splitting verbs in (a) and use each of the verbs in an illustrative sentence in (b).

 

 (a)       ÀTÚNPÍN SÍ ÌSỌ̀RÍ Ọ̀RỌ̀-ÌṢE


Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ẸLẸ́LÀ

Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ALÁÌLẸ́LÀ

bẹ̀wò

dìde

báwí

pàdé

gbàgbọ́

ṣubú

rẹ́jẹ

bẹ̀rẹ̀

tànjẹ

sáré

 

(b)        ÌLÒ Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ẸLẸ́LÀ ÀTI Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ALÁÌLẸ́LÀ NÍNÚ GBÓLÓHÙN

S/N

Ọ̀RỌ̀-ÌṢE

ÌLÒ NÍNÚ GBÓLÓHÙN

I

dìde

Adé dìde lẹ́yìn tí ó jẹun tán.
Ọmọniyì dìde fùú.

ii.

bẹ̀wò

Olùkọ́-àgbà bẹ ilé ẹ̀kọ́ náà .
Àjọ tí ó ń rí sí ètò ìṣúná owó bẹ ilé-iṣẹ́ kan .

iii.

pàdé

Mo pàdé àwọn Ṣọlá lọ́nà ilé.
A jọ pàdé ní ilé Bọ́lá.

iv.

ṣubú

Ṣùpọ̀ ṣubú bí ó ti fẹsẹ̀ kọ́ igi.
Agbábọ́ọ̀lù náà ṣubú lórí pápá.

v.

gbàgbọ́

Mo gba Ọlọ́run gbọ́.
Jídé gbàgbọ́.

vi.

rẹ́jẹ

Bàbá náà fi àgbà rẹ́ mi jẹ.
O kò gbọdọ̀ rẹ́ àbúrò rẹ jẹ.

vii.

tànjẹ

Ẹ̀gbọ́n mi tànjẹ.
Tádé àti Bọ́lá ń tan ara wọn jẹ.

viii.

sáré

Kúdí sáré wọlé.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń sáré tún ọgbà ṣe.

ix.

bẹ̀rẹ̀

Ayọ̀adé tún ti bẹ̀rẹ̀ ẹkún rẹ̀.
Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi lásìkò.

x.

báwí

Bàbá ọmọ rẹ̀ wí.
Kúnlé àbúrò rẹ̀ nítorí ìwà àìtọ́ tí ó hù.

Many of the candidates who attempted this question tackled it well in classifying the verbs into splitting and non splitting verbs in (a) and using each verb appropriately in illustrative sentences in (b).