Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 8

    Ṣàlàyé pàtàkì ìlù àti orin nínú ègèdídá


Observation

 

Candidates were required to discuss the importance of drums and songs in the oral genre as evident in the excerpt.

            Pàtàkì ìlù àti orin nínú Ègè Dídá:
(i)         Wọ́n jẹ́ ohun ìwúrí, àwọn ni ẹ̀mí Ègè Dídá
(ii)        Wọ́n máa ń jẹ́ kí ènìyàn gbọ́wọ́ ijó gẹn̄gẹ
(iii)       Wọ́n máa ń mú ènìyàn fi ìdùnnú hàn láìtijú
(iv)       Orin á máa bu iyì kún Ègè
(v)        Orin lílé ló máa ń fa ìlù lílù; ìlù lílù á sì máa fa ijó jíjó
(vi)       Ìlù gbẹ̀du àti àpàké ni wọ́n máa ń lù sí ègè dídá lásìkò ọdún Orò
(vii)      Oríṣiríṣi ìlù ni a máa ń lù sí ègè dídá níbi àṣeyẹ; lára àwọn ìlù náà ni gángan àti dùndún
(viii)     Afàrò ni ìlù àti orin máa ń jẹ́ níbi tí a bá ti ń dégè
(ix)       Wọ́n máa ń fi wọ́n ki ìdílé àti ìran
(x)        Wọ́n máa ń mú ayẹyẹ dùn gan-an
(xi)       Wọ́n máa ń fi pe àkíyèsí ènìyàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ

Only a few candidates attempted this question.  Their responses to this question were general guesses instead of the specific answers in the text.This portrayed failure to study the text.