Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 10

 

Nínú ewì :Òkìtì Ẹ̀gbin”
(a)      Dárúkọ márùn-ún nínú àwọn ìdọ̀tí àárín ìlú tí akéwì sọ pé ó lè fa àrùn.
(b)     Báwo ni akéwì ṣe sọ pé a lè mójú tó àwọn ìdọ̀tí wọ̀nyí kí wọ́n má bà á fa àrùn.

Observation

 

Candidates were required to mention 5 dirts in the community in (a) and to mention 5 ways to properly handle dirts such that they do not breed germs that causediseases in (b).

(a)      Àwọn ìdọ̀tí àárín ìlú tiakéwì sọ pé ó lè fa àrùn nínú ewì “Òkìtì Ẹ̀gbin”:

  1. òkú ẹran tí a sọ sí ojú/ẹ̀gbẹ́ títì.
  2. ọ̀rá omi,ọ̀rá ìpọ́nkà, ewé irú/ata tí a dà sáàrín ìlú káàkiri.
  3. ìgbọ̀nsẹ̀ ọmọdé àti ti àgbà tí a yà/dà sínú garawa/ike ìkólẹ̀ láàrin ìlú
  4. garawa/ike ìkólẹ̀ tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀ láàrin ìlú tí a kò mójú tó rárá
  5. igbó ṣúúrú ẹ̀yìnkùlé tí a sọ di àkìtàn

 

 (b)    Bí akéwì ṣe sọ pé a lè mójú tó àwọn ìdọ̀tí yìí kí wọ́n má baà fa àrùn:

(i)      kí á máa ṣe ìpalẹ̀mọ́ ẹ̀gbin/ìdọ̀tí ojú/ẹ̀gbẹ́/inú títì/inú garawa ìdalẹ̀sí lóòrèkóòrè.
(ii)      kí ọlọ́pàá máa mú àwọn ará ìlú tí ó bá sọ ọ̀rá/ewé sí ojú/ẹ̀gbẹ́ títì.
(iii)     kí ilé kọ̀ọ̀kan ní ṣáláńgá/ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó bójú mu.
(iv)     kí ilé kọ̀ọ̀kan ní garawa/gorodóòmù fún ìdalẹ̀sí.
(v)      kí a má ṣe sọ igbó ṣúúrú ẹ̀yìnkùlé di àkìtàn.

Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.