Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 5


Fi àpẹẹrẹ mẹ́ta mẹ́ta ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àtúnpín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ wọ̀nyí:
(a)      ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè
(b)     ọ̀rọ̀-orúkọ ibìkan
(d)     ọ̀rọ̀-orúkọ ìgbà
(iv)     ọ̀rọ̀-orúkọ òǹkà
(v)      ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà

Observation

 

Candidates were required to explain and give three examples of each of the sub classification of nouns.

 

Àlàyé àtúnpín-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ pẹ̀lú àpẹẹrẹ

Àtúnpín-ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀-orúkọ

Àlàyé

Àpẹẹrẹ

a) Ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè

Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí a fi máa ń ṣe ìbéèrè/ó máa ń rọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn nínú gbólóhùn ìbéèrè

Kí, Ta, Èwo, Èló, Ibo, Elélòó, abbl.

b) Ọ̀rọ̀-orúkọ ibìkan

Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ ti a lè fi ‘ibo’ ṣe ìbéèrèfún

Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, ọjà, Ifẹ̀, ìta abbl.

d) Ọ̀rọ̀-orúkọ ìgbà

Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó máa ń tọ́ka sí àkókò àti ìgbà kan pàtó

ọ̀sán, alẹ́, òní, ọ̀la, oṣù, ọdún, ìjẹrin, òwúrọ̀, ìrọ̀lẹ́, òru, abbl.

e) Ọ̀rọ̀-orúkọ òǹkà

Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí a máa ń ṣẹ̀dá òǹkà lára rẹ̀

Ení, Èjì, Ẹ̀ta, Ẹ̀rin, Àrún, Ẹ̀fà, Èje, abbl.

ẹ) Ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà

Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó tọ́ka sí nǹkan tí a lè kà

Ilé, Ẹ̀wù, Ìwé, Ọmọ, Ajá, abbl.

Only a few of the candidates who tackled this question were able to explain and give examples of each of the subclassification of nouns