Question 12
Kọ́ àpẹẹrẹ orúkọ àmútọ̀runwá mẹ́sàn-án, kí o sì ṣàpèjúwe méje nínú wọn.
Observation
Candidates were required to list nine (9) Yoruba pre-destined names and describe the metaphysical circumstances surrounding the birth of any seven of them.
The expected responses include:
Àlàyé lórí àwọn orúkọ àmútọ̀runwá:
i. Táye/Táíwò/Táyéwò: Èyí ni ọmọ tí ó kọ́kọ́ wáyé nínú àwọn ìbejì. Òun ni Yorùbá kà sí àbúrò nítorí pé wọ́n gbà pé èkejì rẹ̀ ni ó rán an láti wa tọ́ ayé wò.
ii. Kẹ́hìndé: Èyí ni ọmọ tí ó jáde lẹ́yìn tí Táyé ti jáde nínú ìyá rẹ̀. Òun ni Yorùbá gbà pé ó rán Táyé láti wá tọ́ ilé ayé wò. Ìdí tí wọ́n fi ń pè é ní akẹ́hìndé- gbẹ̀gbọ́n nì yí.
iii. Ọ̀kẹ́: Èyí ni ọmọ tí a bí tí ó wà nínú àpò.
iv. Ìgè: Èyí ni ọmọ tí kò mú orí wáyé nígbà tí a bí i. Ó lè jẹ́ ẹsẹ̀, apá tàbí ìdí ni ó mú wáyé. Ìbí irú àwọn ọmọ wọ̀nyí máa ń nira.
v. Àjàyí: Èyí ni ọmọ tí ó dojú bolẹ̀ nígbà tí a bí i tí a wá yí ojú rẹ̀ padà sókè.
Ìlọ̀rí: Èyí ni ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé òun lóyún rẹ̀ nítorí pé ó ń ṣe nǹkan oṣù títí tí ó fi bí i.
vi. Ẹ̀ta òkò: Èyí ni àwọn ọmọ mẹ́ta tí a bí papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.
vii. Òjó: Èyí ni ọmọ ọkùnrin tí ó gbé olubi rẹ̀ kọ́rùn nígbà tí a bí i. *Àkíyèsí: Àwọn ẹ̀ka Yorùbá kan kì í sọ ọmọ ní Òjó. Àìnà ni wọ́n ń sọ tọkùnrin tobìnrin tí ó bá
la olubi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.
viii. Olúgbódi: Èyí ni ọmọ tí ó ní ìka ọwọ́ tàbí ti` ẹsẹ̀ mẹ́fà.
ix. Ìdòwú: Èyí ni ọmọ tí a bí tẹ̀lé àwọn ìbejì.
x. Babáwándé/Babáwálé/Babájídé/Babátúndé: Ọmọkùnrin tí a bí lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀ àgbà.
xi. Yéwándé/Ìyábọ̀dé/Yéjídé/Yésìdé: Ọmọbìnrin tí a bí lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀ àgbà.
xii. Gísanrín: Ọmọkùnrin tí a bí tí ó wé olubi rẹ̀ mọ́ ìka ọwọ́ rẹ̀ kan.
xiii. Dàda: Ọmọ tí irun rẹ̀ ta kókó láti ìgbà tí a bí i.
xiv. Sàlàkọ́: ọmọkùnrin tí ó fi olubi rẹ̀ pa kájà.
xv. Ọmọ́pẹ́ (nínú): èyí ni ọmọ tí oyún rẹ̀ pẹ́ kọjá oṣù mẹ́wàá kí á tó bí i.
xvi. Amúṣàn-án: ọmọkùnrin eléégún tó wé olubi rẹ̀ mọ́ ọrùn ọwọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgba/pàṣán eégún
xvii. Àìná: ọmọbìnrin tó gbé olubi rẹ̀ kọ́rùn nígbà tí a bí i. * Àkíyèsi: Àwọn ẹ̀ka Yorùbá kan a máa sọ tọkùnrintobìnrin wọn ní Àìná.
xix. Àlàbá: Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Ìdòwú. *Àkíyèsí: Àwọn ẹ̀ka
Yorùbá kan kì í sọ ọmọbìnrin tí a bí lé àwọn ìbejì ní Ìdòwú: Àlàbá ni wọ́n ń sọ ọ́.
The candidates tackled it well.
.