Question 12
Ọ̀nà  wo ni à ń gbà kí àwọn wọ̀nyí?
      (a)      Àgbàlagbà
      (b)     Ẹni tí ó dúró
      (d)     Àwọn tí ó ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́
      (e)      Ẹni tí ó jókòó
      (ẹ)      Ẹni tí ó fẹ́ẹ́ wọlé
      (f)      Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ
      (g)     Ẹni tí ó lóyún sínú
      (gb)    Ẹni tí ìjàǹbá ṣẹlẹ̀ sí
      (h)     Ẹni tí ó pè wá láti wá jẹun
      (i)      Ẹni tí ó wà ní ipò ọlá
Observation
Candidates were required to state the mode of greeting for each of the categories of people listed.
Ọ̀nà tí  à ń gbà kí àwọn wọ̀nyí:
  
| S/N | Àwọn Ènìyàn | Ọ̀nà tí à ń gbà kí wọn | 
| a | Àgbàlagbà | Àjínǹde ara yóò ma jẹ́/Kára ó le/Kẹ́ ẹ pẹ́ o/ Ẹ óò pẹ́ fún wa o/ Ọjọ́ á dalẹ́ o | 
| b | Ẹni tí ó dúró | Ẹ kú ìdúró o | 
| d | Àwọn tí ó ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ | Àjọ ò tú o/ Ẹ kú àpérò/Ẹ kú ìpàdé o. | 
| e | Ẹni tí ó jókòó | Ẹ kú ìjókòó/Ẹ kú ìkàlẹ̀ | 
| ẹ | Ẹni tí ó fẹ́ẹ́ wọlé | Ẹ máa wolẹ̀; ẹ máa rọra | 
| f | Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ | Ẹ kú ewu ọmọ o, Olúwa yóò wò ó/Ẹ kú àrùsọ̀ | 
| g | Ẹni tí ó lóyún sínú | Àsọ̀kalẹ̀ àǹfààní/Àfọ̀n á gbó kó tóó wọ̀/Wẹ́rẹ́ la máa gbọ́ o/A ó gbóhùn ìyá; a óò gbóhùn ọmọ | 
| gb | Ẹni tí ìjàǹbá ṣẹlẹ̀ sí | Ẹ kú yíyọ/ẹ̀yọ Ọlọ́run/A kò níí rí irú rẹ̀ mọ́ o/Ọlọ́run yóò dá ọwọ́ ibi dúró/Ọlọ́run yóò tìkùn ìbànújẹ́/Ẹ pẹ̀lẹ́ o | 
| h | Ẹni tí ó pè wá láti wá jẹun | Yóò/Á gba ibi ire o/Ẹ ṣeun; yóò rẹ̀sọ̀/rọ̀    ṣọ̀mù  | 
| i | Ẹni tí ó wà ní ipò ọlá | Ẹ kú ẹrù àgbà./Ọlá kò níí relẹ̀ o/Kí ẹ̀mí ọlá ó gùn o./ Ẹ ó lo ipò yìí pẹ́ o. | 
Candidates’ performance on this question was commendable.
  
.
