Question 5
 (a)   Dárúkọ márùn-ún nínú oríṣiríṣi ẹ̀yán  tí ó wà nínú àpólà orúkọ
      (b)      Fi àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan kin ìdáhùn rẹ̀  ní 5(a) lẹ́yìn               
      (d)      Lo àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan ni 5(b) nínú  gbólóhùn
  
Observation
Candidates are required to mention five types of qualifiers in a noun phrase in (a), give one example of each type of qualifier in (b) and use each example in an illustrative sentence in (c).
 (a)      Àwọn ẹ̀yán tí ó wà nínú àpólà  orúkọ
    i.        Ẹ̀yán ajórúkọ: oníbàátan, alálàjẹ́
    ii.       Ẹ̀yán aṣàpèjúwe
    iii.      Ẹ̀yán aṣòǹkà 
    iv.      Ẹ̀yán aṣàfihàn
    v.       Ẹ̀yán atọ́ka aṣàfihàn
    vi.      Ẹ̀yán awẹ́-gbólóhùn
          (b)     Àpẹẹrẹ:
    i.        bàbá, tíṣà, nọ́ọ̀sì, káfíńtà
    ii.       rere, ńlá, dúdú
    iii.      mẹ́ta, méjì
    iv.      yìí, yẹn, wọ̀nyí, wọ̀nyẹn
    v.       náà, gan-an, pàápàá 
    vi.      ti Òjó rà; tí à ń wá; tí bàbá kọ́
(d)
| Apẹẹrẹ | Gbólóhùn àfiṣàpẹẹrẹ | 
| bàbá (Ajórúkọ oníbàátan) | Ilé bàbá jóná/Wọ́n wó ilé bàbá | 
| tíṣà (Ajórúkọ alálàjẹ́) | Kọ́lá tíṣà ti dé/Wọ́n pe Kọ́lá tíṣà. | 
| rere | Ọmọ rere ni mí/ mo jẹ́ ọmọ rere. | 
| mẹ́ta, méjì | Àga mẹ́ta wà nínú yàrá/Mojoyin ra àga méjì | 
| yìí | A ti ra ọkọ̀ yìí/Ọkọ̀ yìí wù mí | 
| náà, gan-an, pàápàá | A rí Bọ́lá náà/gan-an/pàápàá | 
| ti Òjó rà | Ilé tí Òjó rà tóbi./A fẹ́ lọ wo ilé tí Òjó rà. | 
Most  candidates ignored this question. Those who attempted it failed to marry their  answers in (a) with those in the (b) part of the question. 
    This led to  poor performance.
