Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 11

Irú ènìyàn wo ni Oyèládùn jẹ́?

Candidates were required to describe Oyeladun’s person as evident in the text.

 

Irú ènìyàn tí Oyèládùn jẹ́:

  1. Àdìó ni orúkọ bàbá Oyèládùn
  2. Àbẹ̀ní ni orúkọ ìyá rẹ̀
  3. Kò bá ọlá kankan ní ilé rárá/Kòlàkòṣagbe ni àwọn òbí rẹ̀
  4. Kíláàsì kẹta ló wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama tí kò fi sí owó lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ láti rán an lọ

sílé-ẹ̀kọ́ mọ́; nítorí bíbọ́ tí iṣé bọ́ lọ́wọ́ bàbá rẹ̀

  1. Àwọn obí rẹ̀ fi í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ́dọ̀ Àlàájà Àdíjá, ìyàwó Ọládẹ̀jọ
  2. Ó gbọ́ èkọ́-ilé, ó sì mọ iṣẹ́-iléé ṣe
  3. Kì í ṣe ọ̀lẹ; òun ló kọ́kọ́ máa ń jí láti ṣe iṣẹ́-ilé kí ẹnikẹ́ni tóó jí ní ilé ọ̀gá rẹ̀
  4. Ó ní ọpọlọ pípé; òun ló ń bá Bọ́sípò, ọmọ ọ́gá rẹ̀, ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀
  5. Kì í ṣe oníṣekúṣe ọmọ; ó gbá Bọ̀sípò létí nígbà tí ìyẹn gbá a nídìí
  6. Ọmọ tó gbọ́n ni; ó kọ̀ láti bá Bọ̀sípò ṣe ọ̀rẹ́ nítorí pé ó gbà pé Bọ̀sípò gọ̀
  7. Kì í ṣe onínàákúnàá ọmọ; ọwọ́ ìyá rẹ̀ ní ó máa ń kó owó tí Bọ́sípò bá fún un pamọ́ sí
  8. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ̀; ó sáré lọ sọ fún àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó gbọ́ pé Ọládẹ̀jọ fẹ́ẹ́ dá bàbá rẹ̀ dúró lẹ́nu iṣẹ́
  9. Ó jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́-ìwé
  10. Òun nìkan ṣoṣo ni àwọn òbí rẹ̀ bí
  11. Ó máa ń ran àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́; ó ń bá ìyá rẹ̀ kiri ọjà

Candidates who attempted the question performed fairly well.