Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 6

Nínú ìtàn “Ìjàpá àti Àáyá Onírùméje”, rọ́ ìtàn láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé ibi tí Ìjàpá ti ṣe ètò láti lọ mú Àáyá onírùméje wá.

Candidates were required to narrate all the preparation Ìjàpá, a character in the folktale put in place in order to capture Àáyá Onírùméje, another character in the folktale. 

Ìtàn bí Ìjàpá ṣe ṣe ètò láti lọ mú Àáyá Onírùméje wá:

(i)         Ní ìlú Ìjàpá, babaláwo wọn dáfá fún ọba pé ó nílò láti fi àáyá onírùméje bọrí kí ìlú lè rójú nígbà tirẹ̀
(ii)        Èyí jẹ́ ìṣòro gidigidi fún ọba nítorí pé kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé ọdẹ kan pa àáyá onírùméjì kí á tóó sọ pé onírùméje
(iii)       Síbẹ̀, ó bẹ gbogbo àwọn ọdẹ láti lọ wá àáyá onírùméje wá: ó sì ṣe ìlérí láti dá ẹni tó bá mú un wá lọ́lá
(iv)       Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, kò sẹ́ni tó rí àáyá ọ̀hún mú wá
(v)      Ọba tún kéde fún gbogbo ìlú lápapọ̀ pé kí wọ́n wá oríṣi àáyá ọ̀hún wá, ó sì ṣe ìlérí láti fún ẹni náà ní ẹ̀bùn ńláńlá, òun yóò sì fi í jẹ oyè Olúọ́dẹ
(vi)       Pàbó ni ìgbíyànjú èyí náà tún já sí
(vii)      Ìjàpá wáá lọ lérí fún ọba pé níwòyí ọ̀túnla, òun yóò mú àáyá onírúméjé tọ̀ ọ́ wá
(viii)     Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣe onírúurú ètò
(ix)       Ó ra ohun ìjà ogun lóríṣiríṣi, ó fọ́n wọn ká sí etí odò láti fi díbọ́n

  1. Ó lọ sí ibi tí àwọn àáyá pọ̀ sí nínú igbó

   (xi)       Ó wá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bíi mẹ́wàá; ó bá wọn dì í pé kí wọ́n fara pamọ́ sí ìtòsí ibi tí àwọn ẹranko náà gbé ń jẹ̀

  1. Ó sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé bí wọ́n bá ti gbọ́ tí òun kígbe, kí wọ́n sáré jáde láti wáá ran òun lọ́wọ́ kí àwọn lè jọ mú àáyá onírùméje
  2. Ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ògìrì tí ó rà pa ara; ó wáá ń díbọ́n bí ẹni pé òun ti kú
  3. Òórùn Ìjàpá ni ó mú kí àwọn àáyá wáá máa pé jọ wò ó
Candidates’ performance was commendable