Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 8

Irú ènìyàn wo ni Adigé jẹ́

Candidates were expected to describe the features of the oral literature chanter as evident in the text.

            Irú ènìyàn tí adígè jẹ́:

(i)         Ẹnikẹ́ni ni ó lé dígè, ìbáà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdé tàbí àgbàlagbà
(ii)        Adígè gbọ́dọ̀ ní ẹ̀bùn ègè dídá
(iii)       Adígè gbọ́dọ̀ ní ẹ̀bùn ohùn dídùn
(iv)       Adígè lè wọ irú aṣọ tí ó bá wù ú lójú agbo
(v)        Adígè gbọ́dọ̀ lè ṣe àkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ
(vi)       Àdígè ní láti jẹ́ aláròjinlẹ̀
(vii)      Adígè gbọ́dọ̀ jẹ́ awíko-n̄-ko-lójú-ọlọ́rọ̀
(viii)    Adígè gbọ́dọ̀ gbọ́n nínú, gbọ́n lẹ́yìn

  1. Adígè gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń fi èdè dárà; kí ó tún ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fi mú ni lọ́kàn
  2. Adígè gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń dápàárá/ṣàwàdà
  3. Ó gbọ́dọ̀ mọ ènìyàn í kì tí orí ẹni tí wọ́n ń kì yóò fi wú tí yóò sì ná owó fún adígè
  4. Ó gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń fi àdúrà/ìwúre kọ̀ọ̀kan há ègè dídá rẹ̀
  5. Ó gbọ́dọ̀ mọ ọpẹ́ í dá fún àwọn tí ó bá ṣe é lóore.

Only a few candidates attempted this question.  Their responses to this question portrayed failure to study the text.