Yoruba Paper 2, Private Candidates 2019

Question 10

 

Ṣé àpèjúwe “Ẹlẹ́jẹ Wèrè” gẹ́gẹ́ bí akéwì ṣe fi hàn nínú ewì “Ẹlẹ́jẹ̀ Wèrè”
Candidates were required to describe “Ẹlẹ́jẹ̀ wèrè” as evident in the poem “Ẹlẹ́jẹ̀ Wèrè”.

Àpèjúwe ẹlẹ́jẹ̀ wèrè bí akéwì ṣe fi hàn nínú ewì “Elẹ́jẹ̀ wèrè”:
(i) Ẹlẹ́jẹ̀ wèrè a máa bínú òdì ṣáá ní gbogbo ọjọ́.

(ii) Alájàkú-akata ni ẹlẹ́jẹ̀ wèrè.

(iii) Bí ẹlẹ́jẹ̀ wèrè bá fẹ́ jà á bọ́ra sí ìhòhò goloto.

(iv) Bí ẹlẹ́jẹ̀ wèrè bá ń bínú, ó lè máa kanrí mọ́lẹ̀, kó máa faṣọ ya.

(v) Ẹlẹ́jẹ̀ wèrè lè bú sẹ́kún, kó máa pariwo.

(vi) Ó lè gbé igi àpólà kó máa fi da àdúgbò rú bó bá ń bínú.

(vii) Ẹlẹ́jẹ̀ wèrè lè bínú sí ọba, ó sì lè bá ìjòyè jà.

(viii) Ó máa ń ja ìjà ẹ̀bi.

(ix) Bí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún un, ọ̀rọ̀ á tún dìjà.

(x) Aríjàgbá ni ẹlẹ́jẹ̀ wèrè, ó lè sọ ìjà di ti ẹni tó ń bá wọn la ìjà/pẹ̀tù síjà.

(xi) Ó lè bínú sí onílé, kó máa ba ilé jẹ́.

(xii) Bónílé bá ní kí ó kó jáde, á tún fara ya.

(xiii) Ẹlẹ́jẹ̀ wèrè lè máa da àdúgbò rú títí tí yóò fi forí gbèpè lẹ́nu àgbàlagbà àdúgbò.

(xiv) Kí ẹlẹ́jẹ̀ wèrè tó làlùyọ, ọ̀nà á jìn nítorí èpè tó ti forí gbà.

(xv) ‘Ṣóólesìn-ín’ ni orúkọ àmútọ̀runwá ẹlẹ́jẹ̀ wèrè.

(xvi) ‘Apatọ́rọ́-da-náhín-sígbó’ lorúkọ àbísọ rẹ̀.

Observation

 

Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.