Yoruba Paper 2, Private Candidates 2019

Question 13

 

Ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ tí a máa ń gbé bí a bá fẹ́ fi ènìyàn jọba ní ilẹ̀ Yorùbá.
Candidates were required to explain the various steps in the installation of a king among the Yorubas.

Àwọn Ìgbésẹ̀ tí a máa ń gbé bí a bá fẹ́ fi ènìyàn jọba ní ilẹ̀ Yorùbá:
(i) Bọ́ba kan ò bá kúrò lórí oyè,ọba mìíràn kò lè jẹ.

(ii) Ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní ìdílé tó ń jọ́ba.

(iii) Àwọn afọbajẹ ìlú yóò pe ìdílé tí oyè ọba kàn láti fa àwọn ọmọ oyè kalẹ̀.

(iv) Bí ọmọ oyè bá ju ẹyọ kan lọ, oyè dídù bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.

(i) Àwọn ọmọ oyè á bẹ̀rẹ̀ sí níí náwó, nára, wọ́n á sì máa wá ojú rere àwọn afọbajẹ.
(ii) Àwọn afọbajẹ yóò béèrè lọ́wọ́ ifá ẹni tí oyè náà tọ́ sí àti àwọn ètùtù tí ó bá yẹ láti ṣe kí ìgbà ọba náà lè tu ìlú lára.
(iii) Nígbà míràn, ọmọ oyè tí ifá mú lè má mọ̀ pé òun ni ifá mú.

(iv) Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, kò sí ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe, àfi kí ó gbà láti jẹ oyè náà.

(v) Bí ó bá ti gbà láti jọba, àwọn awo tí ó wà nídìí ètùtù ṣíṣe yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tiwọn, b.a. gbígbé àwọn igbá ìwà síwájú ọba láti yan ọ̀kan.

(vi) Wọ́n á fi í jọba.

(vii) Bí ó bá jáde ní ìpèbí, yóò ṣe ìwúyè.

Observation

 

Some of the candidates who attempted this question gave detailed explanation of how a king is installed among the Yorubas.