Question 11
Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló fa ikú Jùwọ́n?.
Candidates were expected to narrate the episode that led to the death of Juwon.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó fa ikú Jùwọ́n:
(i) Ọmọ tí Kúnbi bí fún Fẹ́mi ni wọ́n sọ ní Jùwọ́n.
(ii) Jùwọ́n ti ń rá kòrò káàkiri inú ilé wọn.
(iii) Ní ọjọ́ kan, Kúnbi wà nínú ilé ìdáná.
(iv) Fẹ́mi wà ní pálọ̀ tí ó ń wo eré bọ́ọ̀lù lórí ẹ̀rọ
móhùnmáwòrán/tẹlifíṣọ̀n.
(v) Jùwọ́n ń fi bọ́ọ̀lù ṣeré; ó ń rákòrò kiri.
(vi) Jùwọ́n rákòrò tẹ̀lé bọ́ọ̀lù wọ inú yàrá àwọn òbí rẹ̀.
(vii) Bọ́ọ̀lù yí wọ abẹ́ ibùsùn, Jùwọ́n rá kòrò tì í.
(viii) Nígbà tí ó dé abẹ́ ibùsùn, ó rí ìgò funfun kan tí nǹkan wà nínú rẹ̀.
(ix) Ó fà á síta, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí fi ṣeré bí i bọ́ọ̀lù láì mọ̀ pé ìgò àdó ìyá rẹ̀ ni.
(x) Ó gbá a mọ́lẹ̀; ìgò fọ́; àdó sì jáde.
(xi) Ó fọwọ́ kan àdó, ó kígbe oró, ó nà gbalaja sílẹ̀.
(xii) Fẹ́mi sáré wọlé, ó gbé Jùwọ́n, ó di ilé-ìwòsàn ṣùgbọ́n ó ti dòkú.
Observation
Candidates who attempted the question did justice to it.