Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2018

Question 3

Ṣe àlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí, kí o sì fi àpẹẹrẹ méjìméjì gbe àlàyé rẹ̀ lẹ́sẹ̀:

(a) àséèsétán;

(b) àfúnnnupè;

(d) àfàsèsépè;

(e) àfàjàpè;

(ẹ) àfàjàfèrìgìpè.

 

Observation

The question required that candidates should describe some selected manners of articulation and give two examples each of sounds that could be pronounced in the above mentioned manners of sound articulation in Yoruba.

 

(a) Àséèsétán: Afipè àkànmọ́lẹ̀ àti afipè àsúnsí máa ń pínyà, tí èémí á sì gba àárín ẹnu kọjá nígbà tí a bá ń pe ìró kọ́ńsónáǹtì àséèsétán. Kì í sí ariwo kankan tí a lè gbọ́.
Àpẹẹrẹ: [j], [w]/y,w.


(b) Afúnnupè: Àwọn ẹ̀yà-ara tí à ń lò fún ìró èdè pípè á sún mọ́ ara wọn láti fi àlàfo tó kéré sílẹ̀. Èémí á gba àlàfo ẹnu jáde pẹ̀lú ariwo tí a lè fi etí gbọ́.
Àpẹẹrẹ: [f] [s] [h] [ ] /f, s, ṣ, h.


(d) Àfàfàsépè: Ẹ̀yìn ahọ́n àti àfàsé ni a fi ń pè ìró wọ̀nyí. Ẹ̀yìn ahọ́n ni afipè àsúnsí, àfàsé sì ni afipè àkànmọ́lẹ̀.
Àpẹẹrẹ: [g], [k]/ g, k.


(e) Afàjàfèrìgìpè: Iwájú ahọ́n, àárín àjà-ẹnu àti erìgì ni a fi ń pe àwọn ìró wọ̀nyí.
Àpẹẹrẹ: [ ]/ṣ àti j.


(ẹ) Afàjàpè: Ààrín ahọ́n àti àjà-ẹnu ni a fi ń pe àwọn ìró wọ̀nyí. Àárín ahọ́n ni afipè àsúnsí, àjà-ẹnu sì ni afipè àkànmọ́lẹ̀
Àpẹẹrẹ: [j]/y.

 

Some of the candidates described the manners of sound articulation but failed to give the correct sounds for each manner of articulation, this led to loss of marks. Most of the candidates did not attempt this question and those who did performed woefully.