Question 12
Kí ni ààlè? Mẹ́nu ba àwọn ọnà tí àwọn Yorùbá ń gbà lo àalè
Candidates were required to define constraint on personal belongings in Yoruba Tradition and to mention ways by which constraints are placed on personal belongings.
Ààlè jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀nà ìbílẹ̀ tí a fi ń pa àrokò ní ilẹ̀ Yorùbá, òun ni a máa ń lò latí fi dáàbò bo ohun ìní wa kí ẹlòmíràn má baà sọ ọ́ di ti ara rẹ̀.
Àwọn ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà lo ààlè:
(ii) A máa ń pààlè lé obìnrin (ọmọbìnrin, àfẹ́sọ́nà, ìyàwó-ilé) láti kìlọ̀ fún àwọn ọkùnrin pé kí wọ́n má fi ọwọ́ kàn án.
(iii) A máa ń pààlè lé oko kí olè má bàá wọ ibẹ̀.
(iv) A máa ń pààlè lé igi owó (kòkó, ọsàn, obì, abbl) kí olè má baà jí èso rẹ̀ ká.
(v) A máa ń pààlè lé irè oko tí a ti kó àti èyí tí a kò tí ì kó (ọ̀gẹ̀dẹ̀, ọsàn, kòkó, iṣu,àgbàdo, ẹ̀gẹ́, abbl) kí olè má baà jí i kó.
(vi) A máa n lo ààlè láti fi dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ bí olè, àgbèrè abbl ní àwùjọ.
(vii) A máa ń lo ààlè láti fi ìyà tí ó tọ́ jẹ ẹni tí ó bá kọ̀ láti gbọ́ ìkìlọ̀ tí a fi ààlè pa.
(viii) Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí a ń fi ń pa ààlè ni: ìkarahun ìgb́in, àkísà,aṣọ pupa, màrìwò, ìgbálẹ̀, abbl.
Most of the candidates who attempted this question could not define the term, this led to poor performance.