Question 7
Nínú oríkì Ìran Ológbì-ín, ṣàlàyé àwọn ohụn tí a fi ń dá ìran yìí mọ̀.
Candidates were required to explain the identification marks for the Ológbìn-ín lineage.
Àwọn ohun tí a fi ń dá Ìran Ológbìn-ín mọ̀:
(i) Awo eégún ni wọ́n máa ń ṣe.(ii) Wọ́n máa ń suké/ní iké lẹ́yìn.
(iii) Òjò kì í rọ̀ wọ ilé wọn .
(iv) Ilẹ̀ Tápà ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá.
(v) Wọ́n mọ ìlùú lù, wọ́n sì mọ ijóó jó.
(vi) Ìgbàlẹ̀ ni ilé agọ̀ eégún wọn.
(vii) Ológbojò ni babańlá wọn.
(viii) Wọn kì í fobìnrin joyè nígbàlẹ̀.
(ix) Wọ́n fẹ́ràn ẹmu.
(x) Ẹṣin máa ń pọ̀/wà lágbàlá wọn.
(xi) Wọn kì í jẹ ọ̀rúnlá.
(xii) Wọ́n fẹ́ràn látị máa jẹ ẹja.
(xiii) Ẹ̀kú/Agọ̀ ni aṣọ eégún wọn.
(xiv) Iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ, aṣọ híhun àti aṣọ òfì lílù niṣẹ́ wọn.
(xv) Ìlù bàtá ni ìlù wọn.
(xvi) Ojú iná ni wọ́n máa ń gbé olóbi/ibi ọmọ wọn kọ́ sí.
Observation
Candidates’ performance was poor in this question. This suggests that candidates have not studied the prescribed text, Babalọlá’s Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.