Question 9
Báwo ni Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe yọ lọ́wọ́ àwọn agbénipa?
Observation
Candidates were required to recall an episode in the text describing how Òbí and his elder brother, Èjìrẹ́ escaped from the hideout of the kidnappers.
Bí Òbi àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe yọ lọ́wọ́ àwọn agbénipa:
(i) Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wáṣẹ́ lọ sí ìlú Ìbàdàn.(ii) Wọ́n sa gbogbo ipa wọn, pàbó ló bọ́ sí.
(iii) Ọ̀rẹ́ ẹ̀gbọ́n wọn tí ẹ̀gbọ́n wọn fi ọ̀rọ̀ iṣẹ́ wíwá wọn tó létí ní kí wọ́n o pàdé òun ní àfẹ́ẹ́mọ́júmọ́ ní ẹ̀bá ilé ìwòsàn Adéọ̀yọ́.
(iv) Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé ilẹ̀ kò ì tí ì mọ́ púpọ̀ tí wọ́n fi gbéra láti lọ p̀adé rẹ̀.
(v) Wọ́n bọ́ sọ́wọ́ àwọn agbénipa.
(vi) Àwọn géńdé yìí di Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kíríbítí wọ̀ nínú ilé kan nítòsí igbó.
(vii) Wọ́n gbé wọṅ jù síbẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ.
(viii) Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wà níbẹ̀, wọ́n ń wá ọ̀nà àbáyọ sí okùn tí àwọn agbénipa yìí fi dè wọ́n.
(ix) Wọ́n ké pe Olódùmarè/Ọlọ́run kí ó gba àwọn.
(x) Nínú akitiyan àtibọ́ nínú ìdè yìí, wọ́n rí kòtò kan, èyí tí ó gba ènìyàn ní ìdúró.
(xi) Wọ́n dá a lábàá pé kí àwọn kó sínú rẹ̀ kí àwọn tun rí i dí lójú, kí àwọn wá fi agbára tì í sókè bí àwọn agbénipa bá fẹ́ẹ́ kọjá lórí rẹ̀.
(xii) Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
(xiii) Nígbà tí àwọn agbénipa yìí dé, wọ́n ṣí ilẹ̀kùn, wọn kò rí àwọn mẹ́jèèjì mọ́.
(xiv) Wọ́n fìjà pẹẹ́ta láàrin ara wọn, ọ̀rọ̀ di bó-ò-lọ-o-yà-fún-mi.
(xv) Wọ́n jà títí, wọ́n túká, wọ́n sì gbàgbé àti ti ilẹ̀kùn ilé náà nígbà tí wọ́n jáde síta.
(xvi) Lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán, Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rá pálá bọ́ síta, wọ́n sì fara pamọ́ kí ilẹ̀ kó mọ́.
(xvii) Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà ilé wọn lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ pé “Ewu iná kò pa Àwòdì” àwọn.
Candidates who studied this text did a proper recall of the episode as evident in the text Ìgbẹ̀yìn Laláyò ŃTa.