Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2019

Question 8

 

 

Ṣàlàyé bí Ọ̀yún ṣe nalẹ̀ tí ó sì di odò

 

Observation

 

 

Candidates were required to narrate how Ọ̀yún turned to a river in the prescribed text.

Bí Ọ̀yun ṣe nalẹ̀ tí ó sì di odò:
(i) Tańmẹ̀dá tí wọ́n pè ní ẹrú àkọ́rà bàbá wọn ni wọ́n tà nígbà tí kò mọ okoó ro.
(ii) Wọ́n tà á, wọ́n fowó rẹ̀ ra Ìgunnu.
(iii) Ìgunnu bá dóko, ó bá fẹ̀yìn tigi kùkùté.
(iv) Ó ń yẹra rẹ̀ lẹ́pọ̀n wò.
(v) Wọ́n túṅ ní Ìgunnu kò mọ okoó ro.
(vi) Wọ́n tà á, wọ́n mówó rẹ̀, wọ́n fi ra Tan̄dí.
(vii) Òun náà dé oko, bẹ́è ni kò lè ṣe nǹkan kan.
(viii) Wọ́n bá tún ta Tan̄dí, wọ́n powo pọ̀, wọ́n fi ra Ọ̀yun, Ọ̀yun òkòló, onílẹ̀ẹwà.
(ix) Ọ̀yun ní kiní kan lòun yóò ṣe tóun yóò fi gbayì lọ́dọ̀ wọn lóko.
(x) Ọ̀yún bá gbalé babaláwo lọ.
(xi) Babaláwo bá fọ̀pẹ̀lẹ̀ nalẹ̀, Ó sọ ohun tí Ọ̀yun yóò ṣe bí ó bá dóko.
(xii) Ó ní kí Ọ̀yun ó tọ́jú ewé iyá.
(xiii) Kó tọ́jú ewé ẹmi.
(xiv) Kó tún tọ́jú ewé ìgbá.
(xv) Kó tún tọ́jú okùn-olè.
(xvi) Ìgbà tí wọ́n ti ilé dé wọ́n ní Ọ̀yun ò mokoó ro.
(xvii) Wọ́n fẹ́ẹ́ na Ọ̀yun lẹ́yìn ọrùn.
(xviii) Wọ́n ní a rì í yáyá ni tiyá, wọ́n wá Ọ̀yun wọn ò rí i.
(xix) Wọ́n tilé dé, wọ́n tún ní Ọ̀yun ò mokoó ro.
(xx) Wọ́n tún fẹ́ nà án nígi lẹ́yìn ọrùn.
(xxi) Ó léwé ìgbá jọ̀gbá.
(xxii) Pẹ́pẹ́ẹ́pẹ́ ni ewé ẹmi yóò maa lura wọn.
(xxiii) Ọmọ A-nà-gbàjà ni tokùn-olè.
(xxiv) Níbẹ̀ ni Ọ̀yun bá nalẹ̀ ni ó bá dodò.
(xxv) Ni ó bá ń ṣàn lọ, ó ń wọ́ lọ bí ẹri.
(xxvi) Báyìí ni Ọ̀yun ṣe nalẹ̀ tí ó di odò.

The candidates’ performance was poor in this question, this could be attributed to lack of exposure to the text.