Question 6
Nínú ìtàn omọ Aláìgbọ́ràn, báwo ni ọmọaláìgbọ́ràn ṣe bọ́ nínú ìgbèkùn Ìjàpá?
Observation
Candidates were required to recall how the stubborn boy was rescued from Mr Tortoise’s abduction in the folktale.
6. Bí ọmọ aláìgbọràn ṣe bọ́ nínú ìgbèkùn Ìjàpá:(i) Àwọn òbí ọmọ yìí rọ̀ ọ́ pé kí ó má lọ sínú igbó ọdẹ.
(ii) Ó kọ̀ jálẹ̀ pé inú igbó ni òun yóò ti ṣe ọdẹ tòun.
(iii) Ó gba inú igbó lọ.
(iv) Kò pẹ́ tó wọ inú igbó ni òjò ńlá bẹ̀rẹ̀.
(v) Àgbàrá òjò gbé e lọ sí inú ọ̀fìn.
(vi) Ìjàpá rí i, ó sì mú un lọ sí ilé rẹ̀.
(vii) Inú ìlù ni Ìjàpá fi ọmọ yìí pamọ́ sí.
(viii) Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí níí fi ọmọ yìí pawó lóde àríyá.
(ix) Tí Ìjàpá bá ti sọ kọ̀ǹgọ́ sí ìlù, ọmọ yìí yóò bẹ̀rẹ̀ sí níí kọrin “Réré o, Réré ọmọ Olúwo”, àwọn ènìyàn yóò sì máa jó.
(x) Èyí sì sọ Ìjàpá di olókìkí nítorí ìlù rẹ̀ tí ó ń kọrin.
(xi) Ori ọmọ yìí gbé aláwoore kò ó ní ọjọ́ kan.
(xii) Àwọn ènìyàn fura sí Ìjàpá pé ènìyàn ni ó ń fọhùn nínú ìlú rẹ̀.
(xiii) Wọ́n bọ́ Ìjàpá ní àbọ́ yó, wọ́n sì rọ ọ́ ní ẹmu yó ní òde àríyá kan.
(xiv) Ìjàpá sùn lọ fọnfọn.
(xv) Awọn ènìyàn la inú ìlù, wọ̀n sì rí i pé ènìyàn ni Ìjàpá gbé síbẹ̀ tí ó ń kọrin.
(xvi) Wọ́n yọ ọmọdé náà kúrò nínú ìlù wọ́n sì fi ọ̀pọ̀lọ́ rọ́pò rẹ̀; wọ́n se ìlù padà.
(xvii) Báyìí ni ọmọ aláìgbọ́ràn ṣe bọ́ nínú ìgbèkùn Ìjàpá.
The folktale was not properly retold by most Candidates, revealing a shallow knowledge of the text.