Question 11
Ṣe àpèjúwe ilé tí Fẹ́mi ń gbé ní Nàìjíríà.
Candidates were required to describe Fẹ́mi’s house in Nigeria.
Àpèjúwe ilé tí Fẹ́mi ń gbé ní Nàìjíríà:
- Ilé-ilẹ̀ ni ilé náà.
- Ó tóbi, ó sì lẹ́wà púpọ̀.
- Ó ní ilé kékeré lẹ́yìn, tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbé.
- Wọ́n to búlọ́ọ̀kù ìgbàlódé tí ó wọnú ara wọn sí ilẹ̀ àyíká ilé náà.
- Ilé ìgbọ́kọ̀sí wà ní apá òsì géètì.
- Wọ́n gbin oríṣiríṣi arẹwà òdòdó yíká ilé náà.
- Ọkọ̀ mẹ́ta ni wọ́n kó sí ibi ìgbọ́kọ̀sí.
- Àwo alálẹ̀mọ́lẹ̀(táìlì) ní wọ́n lẹ̀ mọ́ gbogbo ilẹ̀ inú ilé náà.
- Gbogbo ohun tí ó wà nínú iyàrá ìgbàlejò ni ó ń dán gbinrin.
- Ọ̀dà funfun ni wọ́n fi kun iyàrá ìgbàlejò.
- Tìmùtìmù tí wọ́n fi awọ aláwọ̀ oriṣiríṣi ṣe ni ó wà nínú iyàrá náà.
- Ẹní àtẹ́ẹ̀ká tí wọ́n ya àmọ̀tẹ́kùn ńlá kan sí wà láàrin iyàrá náà.
- Tábìlì onígíláàsì ni wọ́n gbé lé orí ẹní àtẹ́ẹ̀ká náà.
- Tẹlifíṣàn ńlá gbàǹgbà pẹlẹbẹ kan ni wọ́n fi kọ́ ara ògiri.
- Tábìlì ìjẹun kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kan lápá òsì iyàrá náà tí ó ń dán gbinrin.
- Ilé ìdáná pàápàá dàbí ẹni pé ìlú òyìnbó ni ènìyàn wà.
- Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ni ó wà nínú ilé náà.
Most candidates, who read the prescribed text, gave a proper description of Fẹ́mi’s house in Nigeria and scored good marks.