Question 3
Ṣàlàyé àwọn àbùdá ìṣàpèjúwe ìró fáwẹ́lì wọ̀nyí:
a)ipò àfàsé
b)gíga ahọ́n
d) ìrísí ètè
Observation
This question requires the candidates to the process of vowel production based on the position of the velum (a), the tongue (b) and the lips (d).
(a) Ipò àfàsé
(i) Tí àfàsé bá wá sílẹ̀ yóò fi àyè sílẹ̀ fún èémí tó ń bọ̀ láti gba ọ̀nà ẹnu àti ihò/káà imú tàbí ìmú nìkan jáde. Irú àwọn fáwẹ̀lì tí a pè ní àsìkó yìí yóò jẹ́ fáwẹ̀lì àránmúpè. Àpẹẹrẹ[ã], [ɛ̃], [ɔ̃], [ĩ], [ũ]/an, ẹn, ọn, in, un.
(ii) Tí àfàsé bá gbé sókè, ọ̀nà tó lọ sí káà imú yóò dí pátápátá, èémí á sì gba ẹnu nìkan jáde. Àwọn fáwẹ̀lì tí a pè jáde yóò jẹ́ fáwẹ̀lì àìránmúpè. Àpẹẹrẹ: [a], [e], [ɛ], [i], [o], [ɔ], [u]/ a, e, ẹ, i, o, ọ, u.
(b) Gíga ahọ́n
(i) Nípa lílo apá kan lára ahọ́n tí ó gbé sókè jù lọ nínú ẹnu
iwájú ahọ́n: fáwẹ̀lì iwájú: [i], [e], [ɛ], [ĩ], [ɛ̃]/i, e, ẹ, in, ẹn
àárín ahọ́n: fáwẹ̀lì àárín: [a], [ã]/a, an
ẹ̀yìn ahọ́n: fáwẹ̀lì ẹ̀yìn: [o], [ɔ], [u]/[ɔ̃], [ũ]/o, ọ, u,ọn, un
(ii) Nípa lílo bí apá kan ní ara ahọ́n tí ó gbé sókè jù lọ ṣe gà tó nínú ẹnu: fáwẹ̀lì òkè/àhánupè: [i], [u], [ĩ], [ũ]/i,u,in,un
fáwẹ̀lì ẹ̀bákè:/àhánudíẹ̀pè: [e], [o]/e, o
fáwẹ̀lì ẹ̀bádò/àyanudíẹ̀pè: [e], [ɔ], [ɛ̃], [ɔ̃]/ẹ, ọ, ẹn, ọn
fáwẹ̀lì odò/àyanupè: [a], [ã]/a, an
(d) Ìrísí ètè
(i) Bí a bá fẹ ètè sí ẹ̀yìn tí àlàfo tí ó gùn tí ó sì rí tín-ín-rín wà láàrin wọn: [i], [e], [ɛ], [a], [ĩ], [ɛ̃], [ã]/i, e, ẹ, a, in, ẹn, an.
(ii) Bí ètè bá ṣù jọ tí àlàfo tí ó ṣe roboto sì wà láàrin wọn: [u], [o], [ɔ], [ũ], [ɔ̃]/u, o, ọ, un, ọn.
s
Most candidates performed poorly in tackling this question. Candidates need to devote more time to studying this aspect of the syllabus.
.