Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 6

 

Báwo ni Olúrómbí ṣe fi ìwànwara jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwéré nínú ìtàn “Olúrómbí àti Olúwéré”?

.


This is an oral prose (narrative) question on a desperate female character, Olúrómbí.

Bí Olúrón̄bí ṣe fi ìwàǹwara jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwéré:
(i)      Olúrón̄bí kò tètè finú ṣoyún/rọ́mọ bí./Olúrón̄bí ya àgàn/yàgàn.
(ii)      Ó wá ọmọ títí ṣùgbọ́n pàbó ló já sí.
(iii)     Dípò kó dúró de àsìkò Olódùmarè, ó gba ọ̀dọ̀ Olúwéré lọ.
(iv)     Ó ṣe eléyìí nítorí pé ó rí àwọn tí wọ́n jọ wà nípò àgàn tí wọ́n ti di ọlọ́mọ.
(v)      Pẹ̀lú ìtara/ìwàǹwara ni Olúrón̄bí fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé bí Olúwéré bá fún òun lọ́mọ, òun yóò dá ọmọ náà padà fún un.
(vi)     Ẹ̀jẹ́ yìí jẹ́ ohun ọ̀tun lójú Olúwéré nítorí pé ewúrẹ́ tàbí àgùntàn ni àwọn obìnrin fi máa ń san ẹ̀jẹ́ wọn.
(vii)    Olúrón̄bí lóyún ó sì bí ọmọbìnrin kan.
(viii)   Ó sọ orúkọ ọmọ náà ní Apọ́nbíepo.
(ix)     Ọmọ yìí ń dàgbà.
(x)      Ìyá rẹ̀ kò rántí ẹ̀jẹ́ mọ́.
(xi)     Olúwéré retí pé kí Olúrón̄bí wá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ; kò rí i.
(xii)    Ó gba ilé Olúrón̄bí lọ; ó sì mú Apọ́nbíepo.
(xiii)   Ọmọ yìí bẹ̀rẹ̀ síí sunkún.
(xiv)   Olúrón̄bí bẹ Olúwéré títí; kò gbà.
(xv)    Orin “Gbogbo ènìyàn ń jẹ́jẹ̀ẹ́ ewúrẹ́...”ni Olúwéré fi dá Olúrón̄bí lóhùn pé ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ ni òun tẹ̀lé.

The folktale was not properly retold by most Candidates, revealing a shallow knowledge of the text