Question 5
Kọ àpẹẹrẹ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan irúfẹ́ gbólóhùn wọ̀nyí:
(a) abọ́dé (b) alákànpọ̀ (d) oníbọ̀ (e)àkíyèsi alátẹnumọ ́(ẹ)àtẹnumọ
(f) àyísódì (g) àṣẹ (gb) àlàyé
(h) ìbéèrè (i) ìròyìn
The requirement of this question is to provide one illustrative sentence for each of the ten given sentence types.
Irúfẹ́ gbólóhùn |
Àpẹẹrẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan irúfẹ́ gbólóhùn |
|
Mo ra abọ́ kan ní ọjà/Mo dé. |
|
A wá Olú lọ sí ilé ṣùgbọ́n a kò bá a. |
(d) Oníbọ̀ |
Ìwé tí Bádé rà dára. |
(e)Àkíyèsí alátẹnumọ́ |
Aṣọ ni Tádé fọ̀/Rírà ni bàbá mi ra ilé yìí. |
(ẹ) Àtẹnumọ́ |
Àwọn ni-ìn/ Mo ti gbọ́-ọ̀. |
(f) Àyísódì |
Bímpé kò mu ọtí yó./Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń pè. |
(g) Àṣẹ |
Ẹ dìde (níbẹ̀ yẹn)/Máa bọ̀ (kíákíá)/Dìde kúrò (níbẹ̀). |
(gb) Àlàyé |
Ilé wù mí/Mo fẹ́ẹ́ jẹun/Bọ́lá fẹ́ràn ẹmu |
(h) Ìbéèrè |
Èló ni ẹ̀ ń ta kẹ̀kẹ́ yìí?/Ṣé wọ́n ti dé?/Ó wù ẹ́ tàbí kò wù ẹ́? |
(i) Ìròyìn |
Ó sọ pé òun ń bọ̀/ Wọ́n ní òjó rọ̀ púpọ̀ lánàá. |
Most candidates tackled the question very well and scored good marks. However, topicalized sentence (e) and emphatic sentence (ẹ) are yet to be mastered by the candidates.