Question 9
Báwo ni Àgbà ṣe gba Alóńgẹ́ lọ́wọ́ ikú?
Candidates were required to recall an episode in the text describing how Àgbà saved Alóńgẹ́ from death.
Bí àgbà ṣe gba Alóńgẹ́ lọ́wọ́ ikú:
- Wọ́n lé Òbí àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sílé pé kí wọ́n lọ gba owó ilé-ẹ̀kọ́ wọn wá.
- Kàkà kí wọ́n lọ sí ọ̀nà ilé, odò ẹja ni wọ́n gbà lọ.
- Ní ọjọ́ yìí, wọn kò rí ẹja kankan pa.
- Òbí rọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn máa lọ sí ilé.
- Ọ̀rọ̀ Òbí kò tà léti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
- Dípò kí wọ́n máa lọ sílé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí níí ta ohùn sí ara wọn.
- Òbí sá kúrò lọ́dọ̀ wọn nígbà tí Olúdélé fẹ́ nà án.
- Kò pẹ́ tí Òbí sá kúrò lọ́dọ̀ wọn ni ó gbọ́ ariwo Alóńgẹ́ pé: “Mo gbé o; ejò erè mọ̀ ni o...”.
- Òjòlá/Erè ti lọ́ mọ́ Alóńgẹ́.
- Àwọn ọ̀rẹ́ Alóńgẹ́ gbìyànjú, wọ́n gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òjòlá tí ó fẹ́ẹ́ gbé e mì.
- Lójijì ni Ṣògo-olú àti bàbá ọdẹ kan yọ.
- Bàbá ọdẹ yìí ni ó yin ìbọn lu ejò yìí lẹ́ẹ̀mejì tí ejò sì kú.
- Bàbá ọdẹ bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wí, ó sì kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dẹ odò dé apá ibẹ̀ yẹn mọ́ nítorí pé àwọn ejò pọ̀ ní agbègbè náà.
- Òbí bẹ bàbá ọdẹ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn nípa Alóńgẹ́ tó ń kú lọ.
- Bàbá ọdẹ lo agbára àgbà láti ṣe aájò Alóńgẹ́; ara Alóńgẹ́ sì bọ̀ sípò.
- Báyìí ni àgbà ṣe gba Alóńgẹ́ lọ́wọ́ ikú.
Most candidates performed well as they captured the narrative very well; a sign of proper mastery of the novel by the candidates.