Question 7
Ṣàlàyé mẹ́fà nínú àwọn kókó tí ó sú yọ nínú oríkì “Ìran Ọlọ́fà”.
This oral poetry question was based on the eulogy of the Ọlọ́fà lineage.
Àwọn kókó tí ó sú yọ nínú oríkì Ìran Ọlọ́fà (Mú mẹ́fà nínú wọn)
- Ọlálọmí jẹ ọba ìlú Ọ̀fà lẹ́yìn tí ó borí ìjòyè mẹ́fà nínu ìjàkadì.
- Tápà ni ìyá Ọlọ́fà, Yánrin sì ni orúkọ rẹ̀ ní èdè Tápà.
- Wọn kì í pe ẹ̀fọ́ yánrin lórúkọ; wọ́n ń dà á pè ní látìpá Ọ̀ṣun/látìpá
- Ìjàkadì ni orò wọn.
- Àwọn ni wọ́n ń kì ní ìran Ọlọ́fàmọjọ̀, ìyẹ̀rú ọ̀kín, ọmọ abíṣujóókọ.
- Wọ́n jẹ́ jagunjagun.
- Ọ̀kan nínú àwọn aya Ọlálọmí lóyún nígbà tí Ọlálọmi lọ sójú ogun.
- Wọ́n pe oríṣiríṣi ènìyàn láti lọ mú àgbàdo wá fún ẹṣin ọba ní abẹ́ àká.
- Gbogbo wọn kọ̀ wọn ò lọ.
- Ìyàwó tó lóyún yìí ni ó lọ sí abẹ́ àká láti lọ mú àgbàdo.
- Ìyàwó náà bímọ sí abẹ́ àká.
- Wọ́n wá ọmọ Ọlọ́fà tí yóò lọ kó ọmọ wá sílé wọn ò rí
- Ìwọ̀fà ọba ló lọ kó ọmọ wá sílé
- Nígbà tí Ọlọ́fà padà tí ojú ogun dé, wọ́n ròyìn fún un.
- Ó wá gégùn-ún pé ègún ẹnu ẹrú ni yóò máa rinlẹ̀ lỌ́fà ju ti ọmọbíbí ilé wọn lọ.
- Omi wọ́n ju ọtí lọ ní ilé wọn.
- Lórí igi àràbà ni Ìran Ọlọ́fà ti máa ń ṣe orò àṣegbẹ̀yìn fún òkú tí ó bá kú láàrin wọn.
- Wọ́n máa ń dá aró láti fi rẹ aṣọ
- Oríṣiríṣi ìlù wà ní ààfin Ọlọ́fà tí wọ́n fi máa ń dárayá, b.a. bàtá, aro, abbl.
Most candidates showed a lack of knowledge of the prescribed text: Babalọlá’s Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.