Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 8

 

Ṣẹ àtúpalẹ̀ àyọlò yìí:

Gbogbo yín nì ń júbà lọ́dọ̀ọ gbogbo yín porogodo
Té e m’ọ́rẹ̀ẹ́ mi Àkànmú baba Bèláwù
Ọmọ Ońmọ̀ka
Ìjà àtànà lò ó gbé gbóná
O sì gbé’jà rù gẹngẹ bí ọṣẹ
Ọlálọmí
Ìyọǹyọ
Ọ̀yẹ̀mi
Ọ̀yẹ̀-ẹ-gbọ̀n-ìn-gbọ̀n-ìn.

”.


Candidates were required to analyze an excerpt from the selected text.

Àtúpalẹ̀ Àyọlò:
(i)      Asùnrèmọ̀jé ń fi àyọlò yìí júbà gbogbo ènìyàn tí ó wà lágbo eré.
(ii)      Ọ̀rẹ́ rẹ̀, Àkànmú, wà lára àwọn tí ó ń júbà.
(iii)     Ó sọ pé Àkànmú ni ó bí Bèláwù
(iv)     Ọmọ Ìran Ọlọfà ni Àkànmú.
(v)      Akéwì sọ pé ìjà kì í tán bọ̀rọ̀ nínú àwọn ọmọ Ìran Ọlọ́fà./Ọ̀rọ̀ kì í tán nínú wọn bọ̀rọ̀.
(vi)     Akéwì tún pe ọ̀rẹ́ rẹ̀, Àkànmú, ní Ọlálọmí
(vii)    Ó tún pe Àkànmú ní Ìyọǹyọ
(viii)   Ó tún pe Àkànmú ní Ọ̀yẹ̀mi
(ix)     Ó tún pe Àkànmú ní Ọ̀yẹ̀-ẹ-gbọn-ìn-gbọ̀n-ìn.

Most candidates performed fairly well in answering this question which appeared to them as an “unseen” passage.