Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2019

Question 10

 

Àwọn ilé wo ni akéwì Ṣọ́lé Gbé sọ pé ó jẹ́ àṣìgbé fún ayálégbé?

 

Observation

 

Candidates were required to mention the various houses that may be dangerous to inhabit in the anthology.

Àwọn ilé tí akéwì sọ pé ó jẹ́ àṣìgbé fún ayálégbé nínú ewì “Ṣọ́légbé” ni:

(i) Ilé tí wọ́n ti fi ṣépè.
(ii) Ilé tí wọ́n fi gégùn-ún.
(iii) Ilé tí wọ́n fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́.
(iv) Ilé gidi lórí ilẹ̀ abàmì.
(v) Ilé tí wọ́n fi ohun ìbọ̀dè pilẹ̀ rẹ̀.
(vi) Ilé abàmì lórí ilẹ̀ abàmì.
(vii) Ilé tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ènìyàn pilẹ̀ rẹ̀.
(viii) Ilé tí wọ́n ri ènìyàn mọ́lẹ̀ ní ìpilẹ̀ rẹ̀.
(ix) Ilé tí awuyewuye wà lórí rẹ̀ tàbí lórí ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ ọ lé.
(x) Ilé tí olówó rẹ̀ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ awo/ìmùlẹ̀.
(xi) Ilé tí wọn kò kọ́ dáadáa tí wọ́n kàn fi ọ̀dà kùn, tí ó ń dán lójú lásán.

General guesses were made on various houses that may be dangerous to inhabit but not as evident in the written poem.