Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2019

Question 13

 

    (a) Dárúkọ márùn-ún nínú àwọn oríṣi ìlẹ̀kẹ̀ tí à ń lò ní ilẹ̀ Yorùbá.
    (b) Ṣàlàyé bí a ṣe ń lo ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

 

 

Observation

 

Candidates were required to mention five examples of beads in the Yoruba traditional society in (a) and describe how each bead is used among the Yorubas in (b).

Àwọn oríṣiríṣi ilẹ̀kẹ̀ tí à ń lò ní ilẹ̀ Yorùbá:

(a) Ọya: i. Awọn ọlọ́ya kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹran àgbò; wọn kò sì gbọdò sin àgbò.

(i) Lágídígba
(ii) Iyùn
(iii) Sẹ̀gi
(iv) Ìlẹ̀kẹ̀ okùn
(v) Ìlẹ̀kẹ̀ wẹẹrẹ pupa
(vi) Ìlẹ̀kẹ̀ wẹẹrẹ funfun
(vii) Ṣẹ́ṣẹ́ ẹfun
(viii) Otútù ọpọ̀n
(ix) Àkún
(x) Ìlẹ̀kẹ̀ itún
(xi) Ìlẹ̀kẹ̀ ifà

Bí a ṣe ń lo ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn: (i) Lágídígba: Àwọn obìnrin ni ó máa ń sín in sídìí. Wọ́n máa ń pè é ni bèbè.
(ii) Iyùn: Ilẹ̀kẹ̀ olówó ńlá tí a kì í lò ní gbogbo ìgbà àfi nígbà ìnáwó pàtàkì. Ó tún jẹ́ ilẹ̀kẹ̀ tí a fi ń dá àwọn olóyè mọ̀.
(iii) Sẹ̀gi: Àwọn olóyè, olówó,ọlọ́lá tàbí àwọn tí ó bá ń ṣe ìnáwó pàtàkì ni ó ń lò ó láti fi ṣe ẹ̀ṣọ́.
(iv) Ìlẹ̀kẹ̀ okùn: a fi ń ṣe ẹ̀ṣọ́ sí ìdí ọmọdébìnrin.
(v) Ìlẹ̀kẹ̀ wẹẹrẹ pupa: Awọn olórìṣà Ṣàngó ni wọ́n ń lò ó fún ìdánimọ̀.
(vi) Ìlẹ̀kẹ̀ wẹẹrẹ funfun: Àwọn ọlọ́ṣun máa ń lò ó láti fi ṣe ẹ̀ṣọ́.
(vii) Otútù-ọpọ̀n: Àwọn onífá ni ó máa ń lò ó fúṅ ìdánimọ̀.
(ix) Ṣẹ́ṣẹ́-ẹfun: Àwọn Ọlọ́bàtálá/Olórìṣàńlá àti Olórìṣàoko ni ó ń lò ó fúṅ ìdánimọ̀.
(x) Àkún: Àwọn olóyè ni ó máa ń lò ó láti fi ṣe ẹ̀ṣọ́.
(xi) Ìlẹ̀kẹ̀ itún: Àwọn awo ló ń lò ó fún ìdánimọ̀.
(xii) Ìlẹ̀kẹ̀ ifà: àwọn awo àti olóríṣàńlá ló ń lò ó fún ìdánimọ̀.

Candidates who attempted this question performed poorly.