Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2019

Question 11

 

Ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀dá-ìtàn wọ̀nyí:

(a) Olóyè Tẹjúmówó;
(b) Kọ́lá Ẹgbẹ́dá.

 

Observation

 

Candidates were required to describe the two characters as portrayed by the author in the play.

Àpèjúwe àwọn ẹ̀dá-ìtàn:

Olóyè Tẹjúmówó:
(i) Olówó ni olóyè Tẹjúmówó
(ii) Òun ni bàbá Kúnbi.
(iii) Kúnbi nìkan ni ọmọ tí ó bí.
(iv) Kò rí àyè láti tọ́jú ọmọ.
(v) Ó fi owó ba ọmọ rẹ̀ jẹ́.
(vi) Ohunkohun tí Kúnbi bá béèrè ni ó máa ń fún un.
(vii) Kì í gba ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn rárá.
(viii) Kò kọ́ ọmọ rẹ̀ rárá.
(ix) Ó padà kábàámọ̀ lórí Kúnbi.
(x) Ó ní ilé epo.
(xi) Ó fẹ́ràn fàájì.

(b) Kọ́lá Ẹgbẹ́dá
(i) Òṣìṣẹ́ rélùwéè ni.
(ii) Owó tá Kọ́lá Ẹgbẹ́dá lọ́wọ́/ Kọ́lá kò lówó lọ́wọ́
(iii) Òun ni bàbá Ṣọlá
(iv) Òun náà ló bí Ayọ̀, Túndé àti Káyọ̀dé.
(v) Ó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro.
(vi) Ó káràmáásìkí ọmọ.
(vii) Ó lẹ́mìí ìmoore.
(viii) Ó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
(ix) Ó kàwé tátàtá.
(x) Òun àti ìyàwó rẹ̀ ń tiraka ni láti rán àwọn ọmọ wọn ní ilé-ẹ̀kọ́.
(xi) Ó jèrè ìwà rẹ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ (Àwọn òbí ọkọ Ṣọlá fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ta bàbá Ṣọlá lọ́rẹ).

Description of the characters was satisfactorily handled by the candidates who read the prescribed text. However, some of the candidates mistook Olóyè Ọdúnowó for Olóyè Tẹjúmówó.