Question 10
Àwọn èèwọ̀ wo ni akéwì mẹ́nu bà nínú ewì rẹ̀ “Èèwọ̀ ni”
Observation
Candidates were required to recall various taboos mentioned by the poet evident in the poem “Èèwọ̀ ni”
- Rìbá gbígbà àti owó kíkójẹ jẹ́ èèwọ fún oníṣẹ́ ọba
- Ojo ṣíṣe lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn akéwì jẹ́ èèwọ̀
- Àwọn olórin kò gbọ́dọ̀ kọrin ọ̀fẹ́
- Agbẹjọ́rò kò gbọdọ̀ ṣèrú tàbí kó dalẹ̀ oníbàárà rẹ̀
- Adájọ́ kò gbọdọ̀ gba rìbá
- Onílé kò gbọdọ̀ fi ara ni ayálégbé
- Olùkọ́ kò gbọdọ̀ bá akẹ́kọ̀ọ́ lò pọ̀
- Dókítà kò gbọdọ̀ tú àṣị́rí aláìsàn
- Nọ́ọ̀sì kò gbọdọ̀ kó oògùn tàbí àpò-ẹ̀fọn ilé-ìwòsàn tà
- Atọ́kọ̀ṣe kò gbọdọ̀ ra ayédèrú ẹ̀yà-ara ọkọ̀ fún oníbàárà rẹ̀
- Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀gà
- Ènìyàn kò gbọ̀dọ̀ jẹ dágunró
- Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ gùdùgúdú
- Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ igún
- Ajá kò gbọdọ̀ jẹ ìfun òkété
- Ìgbàgbọ́ kì í jẹ ọ̀pọ̀lọ́
- Mùsùlùmí kò gbọdọ̀ jẹ ajá
- A kì í kí ọba lóòró
- A kì í fi ẹni kúkúrú ṣe awo ẹni tó gùn.
Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.