Question 5
(a) Kọ àpẹẹrẹ atọ́ka tí ó fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àsìkò wọ̀nyí hàn:
(i) atẹ́rẹrẹ;
(ii) bárakú;
(iii) àṣetán;
(iv) àsìkò ọjọ́-iwájú
(v) àìṣetán.
(b) Kọ gbólóhùn kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ tí ó fi ìlò atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àsìkò kọ̀ọ̀kan tí o kọ ní 5(a) hàn.
Observation
Candidates were required to give the tense and aspect markers in (a)
and example of illustrative sentences to show the functions of each of the markers in (b).
(a) Àpẹẹrẹ atọ́ka tí ó fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àsìkò wọ̀nyí hàn:
(i) atẹ́rẹrẹ: ń
(ii) bárakú: máa ń; a máa; ń
(iii) àṣetán: ti; ti ń; ti máa ń; ti máa
(iv) àsìkò ọjọ́-iwájú: yóò; á; máa; ó
(v) àìṣetán: ń, máa ń, a máa
(b) Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ó fi ìlò àwọn atọ́ka hàn:
(i) Atẹ́rẹrẹ:
i. Òjò ń rọ̀.
ii. Mò ń sùn.
iii. Ilé ń jó ní Òkè-ọjà.
iv. À ń retí owó-oṣù wa.
(ii) Bárakú:
i. Táyọ̀ a máa rẹ́rìn-ín.
ii. Olú máa ń tọ̀ sílé.
iii. Bólú ń jẹ kísà nínú oúnjẹ.
(iii) Àṣetán:
i. Mo ti jẹun.
ii. Wọ́n ti máa sọ̀rọ̀ náà fún un.
iii. Wọ́n ti ń kọrin kí a tóó débẹ̀.
iv. Ilẹ̀ ti máa ń rọ̀ kí àgbẹ̀ tóó gbin iṣu.
v. Ọ̀gá ti máa dé sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.
(iv) Àsìkò ọjọ́ iwájú:
i. Ìdáyátù á lọ sí Mẹ́kà.
ii. Túndé yóò dé lọ́la.
iii. A máa pè wọ́n sí ilé wa.
iv. Wọn ó lọ sí oko.
(v) Àìṣetán:
i. Bọ́lá ń fi ọkọ̀ sáré.
ii. Wọ́n máa ń kọrin.
iii. Ilẹ̀ a máa pa òṣìkà.
Only a few of the candidates who tackled this question were able to give examples of illustrative sentences.