Question 3
(a) kọ ẹ̀dà ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-àyálò:
(i) university;
(ii) court;
(iii) biscuit;
(iv) plug;
(v) Hebrew;
(vi) advance;
(vii) soldier;
(viii) blade;
(ix) bread.
(b) Kọ mẹ́ta nínú òfin tí ó de yíyá ọ̀rọ̀ wọ inú èdè Yorùbá.
Observation
Candidates were required to loan the given words into Yoruba in (a) and state 3 rules of loaning words into Yoruba in (b).
(a)
|
Ọ̀rọ̀ láti inú èdè mìíràn |
Ọ̀rọ̀-àyálò ní èdè Yorùbá |
i |
University |
Yunifásítì |
ii |
Court |
Kọ́ọ̀tù |
iii. |
Biscuit |
Bisikíìtì |
iv |
Plug |
Púlọ́ọ̀gì |
v |
Hebrew |
Hébérù |
vi |
Advance |
Àdìfáǹsì |
vii |
Soldier |
Ṣọ́jà |
viii |
Blade |
Bíléèdì |
ix |
Bread |
Búrẹ́dì |
(b) Àwọn òfin tí ó de yíyá ọ̀rọ̀ wọ inú èdè Yorùbá:
i. Kò sí ìṣùpọ̀ kọ́ńsónáǹtì nínú èdè Yorùbá/Kọ́ńsónáǹtì méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kì í tẹ̀lé ara wọn nínú èdè Yorùbá.
ii. Kọ́ńsónáǹtì kì í parí sílébù tàbí ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá
iii. A gbọ́dọ̀ fi kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ̀lì tó bá a mu láti inú èdè Yorùbá rọ́pò kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ̀lì láti inú ọ̀rọ̀ èdè tí a fẹ́ yá lò.
iv. Gbogbo sílébù ọ̀rọ̀ tí a yá wọ inú èdè Yorùbá ni a gbọ́dọ̀ fi àmì ohùn sí bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ.
Many candidates failed to tone mark the loan words in (a) and could not state the rules of loaning words into Yoruba in (b), these led to loss of marks.