Question 11
Sọ̀rọ̀ lórí oríṣiríṣi ìwọ̀sí tí àìlówólọ́wọ́ Àdìó kó bá a.
Observation
Candidates were required to explain how Àdìó, a character, in the play was insulted on different occasions because of his poverty.
Àwọn oríṣiríṣi ìwọ̀sí tí àìlówólọ́wọ́ Àdìó kó bá a:
- Àìlówó lọ́wọ́ Àdìó kò jẹ́ kí ó lè ṣe ojúṣẹ rẹ̀ nílé gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti bàbá ọmọ
- Ìyàwó rẹ̀, Àbẹ̀ní, ni ó ń gbọ́ bùkátà inú ilé.
- Kòbákùngbé ọ̀rọ̀ ni ìyàwó rẹ̀ máa ń sọ sí i kí ó tó fún un lóunjẹ
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ kò jẹ́ kí ó lè rán ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí, Oyèládùn, lọ sílé-ẹ̀kọ́ mọ́.
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ní ó jẹ́ kí Oyèládùn máa bá ìyá rẹ̀ kiri ọjà dípò kí ó máa lọ
sílé-ẹ̀kọ́.
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ní kò jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rù rẹ̀ mọ́ tí ó fi ṣètò làti fi Oyèládùn ṣe ọmọọ̀dọ̀ nílé olówó kan láìgba àṣẹ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ní kò jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ ní ìbọ̀wọ̀ fún un mọ́ tí ó fi jẹ́ pé ìyàwó rẹ̀ ń jáde lọ, tí ó sì rí ọkọ rẹ̀ níjòkòó láìdágbére fún un
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ni ẹ̀rù ṣe bà á nígbà tí ó gbọ́ pé bàbá àgbà kú nítorí pé kò sí owó tí yóò fi ṣòkú
- Owó tí yóò fi ṣe òkú bàbá àgbà tí ó ń wá ni ó ṣe fẹ́ gba àsan-án-lẹ̀ owó-oṣù ọmọ rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ fi ṣe ọmọọ̀dọ̀ láì tíì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bí ẹni fọmọ sọfà.
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ní ó fi gbà láti lọ ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ìdílé tí ọmọ rẹ̀, Oyèládùn, tí ń ṣe ọmọọ̀dọ̀.
- Àìlówólọ́wọ́ rẹ̀ ní ó mú kí ọ̀gá rẹ̀, olóyè Ọládẹ̀jọ, máa bá Àbẹ̀ní, ìyàwó rẹ̀, ní àjọṣepọ̀/ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀.
Candidates who attempted the question performed fairly well.