Question 13
Mẹ́nu ba àwọn ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà ṣe oge láyé àtijọ́.
Observation
Candidates were required to state the traditional ways by which the Yorubas adorn themselves in the olden days.
Àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ṣe oge láyé àtijọ́:
- Ìwẹ̀ wíwẹ̀ láàárọ̀ àti lálẹ́
- Irun dídì/kíkó fún obìnrin
- Irun gígẹ̀/gígé/fífá fún ọkùnrin
- Aṣọ oríṣiríṣi wíwọ̀ fún tọkùnrin tobìnrin
- Ilá ojú kíkọ fún tọkùnrin tobìnrin
- Ara fínfín/sísọ
- Eyín pípa
- Làálì lílé fún obìnrin
- Osùn kíkùn fún obìnrin
- Tìróò lílé fún obìnrin
- Ẹni fífá fún tọkùnrin tobìnrin
- Èékánná gígé fún tọkùnrin tobìnrin
- Etí lílu
- Lílo nǹkan ọ̀ṣọ́ lóríṣiríṣi, b.a. ìlẹ̀kẹ̀, ẹ̀gbà ọwọ́ àti tọrùn, òrùka, abbl.
Some of the candidates who attempted this question did justice to it.