Question 6
Nínú ìtàn “Ìjàpá àti Àgbẹ̀”, kí ló fà á tí ẹ̀yìn Ìjàpá kò fi dán mọ́?
Observation
Candidates were required to give account of why Ìjàpá’s back became rough in the folktale “Ìjàpá àti Àgbẹ̀”.
Ohun tí ó fà á tí ẹ̀yìn Ìjàpá kò fi dán mọ́:
(i) Ọ̀rẹ́ ni Ìjàpá àti Àgbẹ̀; Wọn a máa dáko sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn
(ii) Ní ọdún kan, wọ́n gbin iṣu, ẹ̀gẹ́, ewébẹ̀, ìrẹsì, ikàn àti yangan lọ salalu
(iii) Irè oko Àgbẹ̀ ṣe dáadáa gan-an nítorí pe ó fi gbogbo ara ṣiṣẹ́
(iv) Ìjàpá kò kọ ebè; kò roko; kò sì ri ẹ̀tun fún iṣu rẹ̀
(v) Irè oko Ìjàpá kò ṣe dáadáa rárá ṣùgbọ́n iṣu àgbẹ̀ ta, àgbàdo rẹ̀ gbó, ó yọmọ bọ̀kùà-bọ̀kùà
(vi) Inú bẹ̀rẹ̀ sí níí bí Ìjàpà pé ohun ọ̀gbìn rẹ̀/tirẹ̀ kò ṣe dáradára
(vii) Ó pinnu pé iṣu òun ṣe dáadáa tàbí kò ṣe dáadáa o, kí òun ṣà ti jẹ iyán ni tòun
(viii) Ó bẹ̀rẹ̀ síí wa iṣu; ó ń ya àgbàdo; ó ń fẹ́ ẹ̀fọ́ ní oko àgbẹ̀ bí ẹni pé tirẹ̀ ni
(ix) Àgbẹ̀ rí ‘ọwọ́’ nínú oko rẹ̀; ó bi Ìjàpá ṣùgbọ́n Ìjàpá búra pé òun kò wọ inú oko rẹ̀
(x) Ìjàpá kò jáwọ́; ni Àgbẹ̀ ba gba ilé babaláwo lọ
(xi) Àgbẹ̀ di òpó Ọ̀sányìn Ẹlẹ́sẹ̀méje mú gẹ́gẹ́ bí bàbáláwo ṣe gbà á ní ìmọ̀ràn
(xii) Ìjàpà tún lọ sí okọ Àgbẹ̀ lóru bí ó ti máa ń ṣe; Ọ̀sányìn nà án ní ààjà lẹ́yìn; igbá ẹ̀yìn rẹ̀ sì fọ́
(xiii) Bí ó ṣe ń wọ́ lọ sígbó ni ó rí Aáyán, Èèrà àti Ìkamọ̀dù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ mọ́lemọlé
(xiv) Ìjàpá bẹ̀ wọ́n, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí bá a dán ẹ̀yin rẹ̀
(xv) Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí níí bú Ìkamọdù pé òórùn rẹ̀ pọ̀ jù
(xvi) Ìkamọ̀dù bínú; ó sì fi ẹ̀yìn Ìjàpá sílẹ̀ gákugàku
(xvii) Báyìí ni ẹ̀yìn Ìjàpá kò ṣe dán mọ́.
Candidates who read the text gave detailed account of how Ìjàpá’s back became rough.