Question 12
Ṣe àlàyé ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ nínú ayò títa:
(a) ọmọ-ayò;
(b) òdù.
Observation
Candidates were required to describe the terms in a Yoruba traditional game “Ayò-títa”.
(a) Ọmọ-ayò:
(i) Igi eléso kan báyìí tí ó ni èso tí ó ń dán ni ó ń pèsè ọmọ-ayò
(ii) Ọmọ-ayò yìí ni a máa ń lé sí ojúlé ọpọ́n-ayò
(iii) Ojúlé méjìlà (mẹ́fà ní apa ọ̀tún, mẹ́fà ní apá òsì) ni ọpọ́n-ayò máa ń ní
(iv) Ọmọ-ayò mẹ́rin mẹ́rin ni à ń lé sínú ojúlé ọpọ̀n-ayò kọ̀ọ̀kan
(v) Ọmọ-ayò yìí ni àwọn ọ̀tayò máa ń ta, tí wọ́n máa ń jẹ/kó tí kò bá ju méjì tàbí mẹ́ta lọ níbi tí ó parí sí; apá ọ̀tún ni wọ́n máa ń ta á sí
(vi) Bí kò bá sí ọmọ-ayò ní àrọ́wọ́tó, a máa ń lo kóró iṣin tàbí òkúta akọ wẹ́wẹ́ tó ń dán.
(b) Òdù:
(i) Àwọn ọ̀tayò tó já fáfá ni ó máa ń kún òdù
(ii) Kíkún òdù ni pé kíkó ọmọ-ayò jọ sójúlé ayò kan ní ọ̀dọ̀ ẹni
(iii) Bí a ti ń kún òdù ni a ó máa kà á kí ó má báa fò, kí ó má sì forí ṣọ́npọ́n
(iv) Àwọn ọmọ-ayò tí a kó jọ yìí lè yí ojúlé-ayò tí ó wà lójú ọpọ́n ayò po lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì
(v) Bí òdù kò bá jẹ, ó forí ṣọ́pọ́n nìyẹn
(vi) Bí òdù bá yíká ilé àwọn òǹtayò méjèèjì tí ó sì padà wá sí ilé ẹni tí ó kún òdù náà, á jẹ́ pé òdù náà fò/tàbí pé ó jù nìyẹn
(vii) Òǹtayò kò lè fi òdù jẹ ayò ju ihò méjì, mẹ́ta, mẹ́rin tàbí márùn-ún lọ
Candidates who attempted this question performed fairly well.