Question 10
Sọ àwọn ìpalára tí akéwì sọ pé màgòmágó ìdánwò ń fà gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ yọ nínú ewì “Màgòmágó Ìdánwò”
Observation
Candidates were tasked to explain the consequences of examination malpractices as evident in the poem.
Ìpalára tí akéwì sọ pé màgòmágó ìdánwò ń fà:
- Màgòmágó ìdánwò ń pa iná ètò-ẹ̀kọ́
- Ó máa ń sọ ni di ẹni yẹpẹrẹ nígbẹ̀yìn
- Ó máa ń ba aṣọ àlà ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀-èdè jẹ́
- Ó máa ń fa ikú àìtọ́jọ́
- Ó máa ń sọni di olóríburúkú
- Kì í jẹ́ kí á lè dáàbò bo ìwé-ẹ̀rí tí a gbà
- Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jáde ìwé mẹ́wàá kì í lè sọ èdè Òyìnbò tí ó já gaara
- Ó má ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọn yóò fi di jàgùdà páálí
- Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lé ọmọ tí ọwọ́ bá tẹ̀ kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́
- Ó máa ń sọni di àkọ̀tì láàrin ẹgbẹ́/ọ̀gbà
- Ó máa ń sọni di aláàbọ̀ ẹ̀kọ́
- Ó máa ń bani lórúkọ jẹ́
- O máa ń dójú ti ni
- Àtunbọ̀tan àwọn tíṣà tó kópa nínú màgòmágó ìdánwò kì í dára
This question was poorly answered by most candidates who, obviously, did not study the prescribed text. General guesses based on societal knowledge were made.