Question 12
Ọ̀nà wo ni à ń gbà kí àwọn wọ̀nyí?
(a) Àgbàlagbà
(b) Ẹni tí ó dúró
(d) Àwọn tí ó ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́
(e) Ẹni tí ó jókòó
(ẹ) Ẹni tí ó fẹ́ẹ́ wọlé
(f) Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ
(g) Ẹni tí ó lóyún sínú
(gb) Ẹni tí ìjàǹbá ṣẹlẹ̀ sí
(h) Ẹni tí ó pè wá láti wá jẹun
(i) Ẹni tí ó wà ní ipò ọlá
Observation
Candidates were required to state the mode of greeting for each of the categories of people listed.
Ọ̀nà tí à ń gbà kí àwọn wọ̀nyí:
S/N |
Àwọn Ènìyàn |
Ọ̀nà tí à ń gbà kí wọn |
a |
Àgbàlagbà |
Àjínǹde ara yóò ma jẹ́/Kára ó le/Kẹ́ ẹ pẹ́ o/ Ẹ óò pẹ́ fún wa o/ Ọjọ́ á dalẹ́ o |
b |
Ẹni tí ó dúró |
Ẹ kú ìdúró o |
d |
Àwọn tí ó ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ |
Àjọ ò tú o/ Ẹ kú àpérò/Ẹ kú ìpàdé o. |
e |
Ẹni tí ó jókòó |
Ẹ kú ìjókòó/Ẹ kú ìkàlẹ̀ |
ẹ |
Ẹni tí ó fẹ́ẹ́ wọlé |
Ẹ máa wolẹ̀; ẹ máa rọra |
f |
Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ |
Ẹ kú ewu ọmọ o, Olúwa yóò wò ó/Ẹ kú àrùsọ̀ |
g |
Ẹni tí ó lóyún sínú |
Àsọ̀kalẹ̀ àǹfààní/Àfọ̀n á gbó kó tóó wọ̀/Wẹ́rẹ́ la máa gbọ́ o/A ó gbóhùn ìyá; a óò gbóhùn ọmọ |
gb |
Ẹni tí ìjàǹbá ṣẹlẹ̀ sí |
Ẹ kú yíyọ/ẹ̀yọ Ọlọ́run/A kò níí rí irú rẹ̀ mọ́ o/Ọlọ́run yóò dá ọwọ́ ibi dúró/Ọlọ́run yóò tìkùn ìbànújẹ́/Ẹ pẹ̀lẹ́ o |
h |
Ẹni tí ó pè wá láti wá jẹun |
Yóò/Á gba ibi ire o/Ẹ ṣeun; yóò rẹ̀sọ̀/rọ̀ ṣọ̀mù |
i |
Ẹni tí ó wà ní ipò ọlá |
Ẹ kú ẹrù àgbà./Ọlá kò níí relẹ̀ o/Kí ẹ̀mí ọlá ó gùn o./ Ẹ ó lo ipò yìí pẹ́ o. |
Candidates’ performance on this question was commendable.
.