Question 3
Tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ìpajẹ wà nínú ìṣẹ̀dá wọn nínú àyọkà ìsàlẹ̀ yìí kí o sì sọ ìró tí a pajẹ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Moyọ̀sọ́rẹ kúrò ní ojúde ọba; ó gba ọ̀nà ilé rẹ̀ lọ sí ìdíkọ̀. Lójú ọ̀nà, ó rí àwọn tí ó ń jẹ̀ṣẹ̀ ní etídò. Ti pé ó wọṣọ funfun tí ó sì tún fẹ́ ya ọ̀dọ̀ ìyakọ rẹ̀ kò tilẹ̀ wo ibẹ̀ rárá. Ó yà kọ̀wé sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀.
Observation
This question requires the candidates to identify words which contain elision of sound in the passage and mention the elided sound in each of those words.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ìpajẹ wà nínú ìṣẹ̀dá wọn àti ìró tí a pajẹ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn:
S/N |
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ìpajẹ wà nínú ìṣẹ̀dá wọn |
Ìró tí a pajẹ́ níṅú wọn |
a |
Moyọ̀sọ́rẹ |
I |
b |
ojúde |
O |
d |
ìdíkọ̀ |
ọ |
e |
lójú |
I |
ẹ |
jẹ̀ṣẹ́ |
A |
f |
etídò |
O |
g |
wọṣọ |
A |
gb |
ìyakọ |
ọ |
h |
kọ̀wé |
I |
i |
sílẹ̀ |
I |
Most candidates performed fairly well in tackling this question.