Question 7
Nínú Oríkì Ìran Ajíbógundé”, ṣàlàyé bí Abímbéṣú ṣe jogún ìran Òpó.
Observation
This oral poetry question was based on how Abímbéṣú inherited the lineage of Òpó.
Bí Abímbéṣú ṣe jogún ìran Òpó:
- Wọ́n ní kí wọn ó gbẹ́ ọnà lọ sí Ọ̀yọ́ láyé ọba Abíọ́dún
- Làgbàyí ará Ọ̀jọwọ̀n náà gbẹ́ tirẹ̀ lọ
- Ọgọ́jọ òpó ni ó gbẹ́
- Ó ní wọn ó ṣe ọgọ́rin láyaba/ní ayaba
- Ó ní kí wọ́n ṣe àádọ́rin ní òsì-ẹ̀fà
- Ó ní kí wọ́n ṣe ẹ̀wá/mẹ́wàá yòókù ní àwọn tí yóò máa gbálẹ̀ Ṣàngó ní ọrọọrún
- Òpó kò fọhùn rí láyé ọba Abíọ́dún ṣùgbọ́n òpó fọhùn ní ọjọ́ tí ọba wàjà/ilé ségi ní ààfin Ọ̀yọ́
- Ẹlẹ́rú ń jogún ẹrú
- Oníwọ̀fà ń jogún ìwọ̀fà
- Aláṣọ ń jogún aṣọ
- Òpó wá róṣọ, Òpó gbàjá
- Òpó kan duduudu níwájú ọba
- Òpó wá káwọ́ lérí, ó ń sunkún
- Òpó ní òun ò réèyàn tí yóò jogún ìran baba òun
- Abímbéṣú ló wá jogún ìran òpó
- Báyìí ni Abímbéṣú ṣe jogún ìran òpó
Most candidates showed a lack of knowledge of the prescribed text: Babalọlá’s Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.