Question 4
Sọ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a fàlà sí nídìí nínú gbolóhùn wọ̀nyí wà.
(a) Wàhálà Olú pọ̀.
(b) Mo pa ̀kì ara mi.
(d) Má wàhálà mi.
(e) Àwọn tí à ń retí ti dé.
(ẹ) Ọmọ wù mí.
(f) Bọ́lá Ìbàdàn ga ju Bọ́lá Èkó lọ.
(g) Aṣọ pupa ni Olú wọ̀.
(gb) Ẹ̀bùn wà ní inú mọ́tò.
(h) Ó se iṣu ṣùgbọ́n kò jẹ ẹ́
(i) Ilé wa ni Bísí ń gbé.
Observation
Candidates were required to state the grammatical class of the underlined words in
each sentence.
Ìsọ̀rí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fàlà sí nídìí
(a) ọ̀rọ̀-orúkọ
(b) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ/ọ̀rọ̀-orúkọ
(d) ọ̀rọ̀-ìṣe
(e) ọ̀rọ̀-arọ́pò-afarajórúkọ/ọ̀rọ̀-orúkọ
(ẹ) ọ̀rọ̀-arópò-orúkọ/ọ̀rọ̀-orúkọ
(f) ọ̀rọ̀-orúkọ
(g) ọ̀rọ̀-àpèjúwe
(gb) ọ̀rọ̀-atọ́kùn
(h) ọ̀rọ̀-asopọ̀
(i) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ/ọ̀rọ̀-orúkọ
Most candidates who attempted this question performed fairly well while a few of them mistook grammatical classes for word classes.