Question 6
Nínú ìtàn “Ìjàpá àti Àkèré”, Bí ayọ̀ àyọ̀jù ṣe jẹ́ kí Àkèré ṣẹ́ ní itan
Observation
This is a recall narration of how Àkèré, a character in the folktale lost his thigh to overzealousness.
Bí ayọ̀ àyọ̀jù ṣe jẹ́ kí Àkèré ṣẹ́ ní itan:
(i) Ní ayé àtijọ́ Ìjàpá àti Àkèré jọ ń ṣọ̀rẹ́
(ii) Agbẹ́gilére ni Àkèré ṣùgbọ́n àgbẹ̀ ni Ìjàpá
(iii) Àkèré gbajúmọ̀ ó sì já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀
(iv) Ìlú òkèèrè ni Àkèré ń gbé ṣùgbọ́n ilé ni Ìjàpá ti ń bá iṣẹ́ àgbẹ̀ rẹ̀ lọ
(v) Nígbà tó ṣe, ọba ìlú Ìjàpá wàjà
(vi) Ìdílé Àkèré ni ó kàn láti jẹ ọba
(vii) Àwọn afọbajẹ dífá, ifá sì mú Àkèré gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jọba
(viii) Inú Ìjàpá kò dùn sí èyí, ó sì pinnu láti wá ọ̀nà láti tan Àkèré pa
(ix) Ìjàpá lọ bá Àkèré ní ìlú ibi tí ó wà bí ẹni pé ó fẹ́ bá a dáwọ̀ọ́ ìdùnnú. Àkèré fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí i
(x) Àwọn afọbajẹ ránṣẹ́ sí Àkèré pé kí ó wá jọba, inú rẹ̀ dùn púpọ̀ sí èyí, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí palẹ̀mọ́ láti lọ
(xi) Àwọn ọ̀rẹ́ Àkèré tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ̀lú àwọn onílù, òun náà sì gun ẹṣin funfun
(xii) Inú Ìjàpá kò dùn, ẹ̀rín ìyàngì ló ń rín, ó sì ń wá ọ̀nà láti ta Àkèré ní ìjàǹbá
(xiii) Ìjàpá sọ fún Àkèré pé kí ó máa fò lórí ẹṣin láti fi ayọ̀ rẹ̀ hàn
(xiv) Ibi tí Àkèré ti ń dárà lórí ẹṣin ni ó ti fa ìjánu ẹṣin, èyí sì mú kí òun àti ẹṣin kó sí inú kòtò
(xv) Ẹṣin ṣubú lé Àkèré lórí, itan rẹ̀ sì rún wómúwómú
(xvi) Báyìí ni Àkèré ṣe fi ayọ̀ àyọ̀jù ṣẹ́ ara rẹ̀ ní itan
The folktale was not properly retold by most candidates, revealing a shallow knowledge of the text.