Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 10

    Kí ni ohun tí ó fà á tí ọba Ìlúfẹ́milóyè kò fi lè mú àyípadà rere bá àwọn ará ìlú Májíyàgbé nínú ewì “Ìlú Májìyàgbé”


Observation

Candidates were required to state various reasons why the king could not help to bring about the expectations of the citizens as evident in the poem Ìlú Májìyàgbé”

Ohun tí ó fà á tí Ìlúfẹ́milóyè ko ṣe lè mú àyípadà bá àwọn ará ìlú Májìyàgbé:

  1. Ìlú Májìyàgbé kò tùbà bẹ́ẹ̀ ni kò tùṣẹ.
  2. Àwọn ará ìlú ń retí ọba tí ó lè bá wọn táyé ṣe nínú ọmọ oyè méjì tó wà(Ìlúfẹ́milóyè àti Jọ́láyẹmí)
  3. Bínú ṣe rí ni obì ń yàn; lẹ́yìn àwọn ìgbésẹ̀ àwọn afọbajẹ, Ìlúfẹ́milóyè ló di ọba tuntun
  4. Gbogbo ìlú gbà pé òun nìkan ni ó lè mú àyípadà rere bá ìlú, tí yóò sì tún ohun gbogbo tó ti bàjẹ́ ṣe
  5. Lẹ́yìn ìgbà tí kábíèsí ti lo ọdún kan lórí oyè, ìlú kò yí padà sí rere, gbogbo nǹkan tún ń bàjẹ́ ju bí Ìlúfẹ́milóyè ṣe bá a kí ó tóó jọba lọ
  6. Kò yé ọba mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò yé àwọn ìjòyè mọ́
  7. Olóyè  Ọ̀tún ni ó wáá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni ó ń bínú sí ìlú tí àwọn ará ìlú ò sì mọ̀
  8. Olóyè Ọ̀tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Olúwa kì í fẹ́ kí wọn fi ènìyàn rọ́pò/dípò Òun
  9. Òun ni ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni wọ́n ṣi ọba lọ́nà nítorí pé wọ́n gbà pé kábíèsí nìkan ló lè ṣe é
  10. Lẹ́yìn èyí ni gbogbo ìlú àti kábíèsí wá mọ àṣìṣe wọn; wọ́n wá gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é

 

Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the poem.