Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 9

    wo ni Mọrèmi ṣe dé ìlú Ìlàá


Observation

 

Candidates were required to discuss how Mọrèmi’s journeyed to Ila town.

Bí Mọrèmi Ṣe dé Ìlú Ìlàá:

  1. Ọ̀kànbí, Àrólé Atẹ̀wọ̀nrọ̀, ni ó lé Mọrèmi kúrò nílùú Ilé-Ifẹ̀
  2. Wọ́n lé e lọ sí Elùjù-méje
  3. Ìdí tí wọn fi lé e ni pé ó ṣe agbátẹrù bí àwọn obìnrin ṣe jà fún òmìnira wọn
  4. Fádiọ́rà ni olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ méje tí wọ́n sin Mọrèmi kúrò nílùú lọ sí Elùjù-méje
  5. Lójú ọ̀nà ni wọn ti pàdé ìyá-lódò
  6. Ìyá-lódò sì rọ Fádiọ́rà pé kí ó mú Mọrèmi lọ sílé Ìlàá lọ́dọ̀ Ọ̀ràngún dípò kí ó mú un lọ sí Elùjù-méje
  7. Pẹ̀lú àṣẹ tí ìyá-lódò fi bá Fádiọ́rà sọ̀rọ̀; ó gbọ́ síyàá lẹ́nu
  8. Lẹ́yìn àkùkọ ìdájí méjì bí wọn ti ń sún mọ́ etí ìlú, Fádiọ́rà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ yòókù padà lẹ́yìn Mọrèmi
  9. Mọrèmi wáá ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí ìlú Ìlàá, lóun nìkan
  10. Ekòló gòdògbà kan jáde sí ẹsẹ̀ Mọrèmi
  11. Ekòló yìí ni ó ṣe atọ́nà rẹ̀ dé ìlú Ìlàá
  12. Wọ́n gba Mọrèmi tọwọ́tẹsẹ̀ nílùú Ìlàá
  13. Báyìí ni Mọrèmi ṣe dé ìlú Ìlàá

Candidates’ performance in this question was commendable.