Question 13
Mẹ́nu ba àwọn ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà ṣe oge láyé àtijọ́.
Observation
Candidates were required to state the traditional ways by which the Yorubas adorn themselves in the olden days.
Àwọn ọ̀nà tí ìran Yorùbá ń gbà ṣe oge ní ìgbà àtijọ́:
- Ìwẹ̀ wíwẹ̀ láàárọ̀ àti lálẹ́
- Irun dídì/kíkó fún obìnrin
- Irun gígẹ̀/gígé/fífá fún ọkùnrin
- Aṣọ ìmúròde oríṣiríṣi wíwọ̀ fún tọkùnrin tobìnrin(gèlè, ìpèlé, ìborùn, fìlà, abbl.)
- Ilà ojú kíkọ fún tọkùnrin tobìnrin
- Ara fínfín/sísọ
- Eyín pípa
- Làálì lílé fún obìnrin
- Osùn kíkùn fún obìnrin
- Tìróò lílé
- Yẹtí, òrùka, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ti ọrùn lílò
- Ìlẹ̀kẹ̀ lílò
- Ìrùkẹ̀rẹ̀ lílò
- Ilà abẹ́ kíkọ
Candidates who attempted this question performed fairly well. Some of them mixed up the modern form of adornment with the ancient forms while tackling the question