Question 4
(a) Ṣe àtúnpín àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí sí abẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe ẹlẹ́là àti aláìlẹ́là:
(i) dìde
(ii) bẹ̀wò
(iii) pàdé
(iv) ṣubú
(v) gbàgbọ́
(vi) rẹ́jẹ
(vii) tànjẹ
(viii) sáré
(ix) bẹ̀rẹ̀
(x) báwí
(b) Lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó wà ní 4(a) nínú gbólóhùn
Observation
Candidates were required to classify the given verbs into splitting and non splitting verbs in (a) and use each of the verbs in an illustrative sentence in (b).
(a) ÀTÚNPÍN SÍ ÌSỌ̀RÍ Ọ̀RỌ̀-ÌṢE
Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ẸLẸ́LÀ |
Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ALÁÌLẸ́LÀ |
bẹ̀wò |
dìde |
báwí |
pàdé |
gbàgbọ́ |
ṣubú |
rẹ́jẹ |
bẹ̀rẹ̀ |
tànjẹ |
sáré |
(b) ÌLÒ Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ẸLẸ́LÀ ÀTI Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ALÁÌLẸ́LÀ NÍNÚ GBÓLÓHÙN
S/N |
Ọ̀RỌ̀-ÌṢE |
ÌLÒ NÍNÚ GBÓLÓHÙN |
I |
dìde |
Adé dìde lẹ́yìn tí ó jẹun tán. |
ii. |
bẹ̀wò |
Olùkọ́-àgbà bẹ ilé ẹ̀kọ́ náà wò. |
iii. |
pàdé |
Mo pàdé àwọn Ṣọlá lọ́nà ilé. |
iv. |
ṣubú |
Ṣùpọ̀ ṣubú bí ó ti fẹsẹ̀ kọ́ igi. |
v. |
gbàgbọ́ |
Mo gba Ọlọ́run gbọ́. |
vi. |
rẹ́jẹ |
Bàbá náà fi àgbà rẹ́ mi jẹ. |
vii. |
tànjẹ |
Ẹ̀gbọ́n mi tàn mí jẹ. |
viii. |
sáré |
Kúdí sáré wọlé. |
ix. |
bẹ̀rẹ̀ |
Ayọ̀adé tún ti bẹ̀rẹ̀ ẹkún rẹ̀. |
x. |
báwí |
Bàbá bá ọmọ rẹ̀ wí. |
Many of the candidates who attempted this question tackled it well in classifying the verbs into splitting and non splitting verbs in (a) and using each verb appropriately in illustrative sentences in (b).