Question 2
(a) Kí ni afipè àsúnsí?
(b) Dárúkọ afipè àsúnsí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì wọ̀nyí:
(i) t
(ii) m
(iii) k
(iv) j
(v) y
(vi) l
(vii) ṣ
(viii) f
(ix) gb
Observation
Candidates were required to define the term active articulators in (a) and identify the active articulators of the given consonant sounds in (b).
(a) Afipè àsúnsí ni àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí wọ́n máa ń gbéra nígbà tí a bá ń gbé ìró jáde/pe ìró. (Ìsàlẹ̀ ẹnu ni àwọn ẹ̀yà ara yìí máa ń wà).
(b)
S/N |
Kọ́ńsónáǹtì |
Afipè Àsúnsí |
i |
t |
iwájú ahọ́n |
ii |
m |
ètè ìsàlẹ̀ |
iii |
k |
ẹ̀yìn ahọ́n |
iv |
j |
ìwájú/àárín ahọ́n |
v |
y |
àárín ahọ́n |
vi |
l |
ìwájú ahọ́n |
vii |
ṣ |
àárín ahọ́n |
viii |
f |
ètè ìsàlẹ̀ |
ix |
Gb |
ètè ìsàlẹ̀, ẹ̀yìn ahọ́n |
Most of the candidates who attempted this question defined the active articulators but failed to identify the active articulators of the given consonants, this led to poor performance.