Question 10
Nínú ewì :Òkìtì Ẹ̀gbin”
(a) Dárúkọ márùn-ún nínú àwọn ìdọ̀tí àárín ìlú tí akéwì sọ pé ó lè fa àrùn.
(b) Báwo ni akéwì ṣe sọ pé a lè mójú tó àwọn ìdọ̀tí wọ̀nyí kí wọ́n má bà á fa àrùn.
Observation
Candidates were required to mention 5 dirts in the community in (a) and to mention 5 ways to properly handle dirts such that they do not breed germs that causediseases in (b).
(a) Àwọn ìdọ̀tí àárín ìlú tiakéwì sọ pé ó lè fa àrùn nínú ewì “Òkìtì Ẹ̀gbin”:
- òkú ẹran tí a sọ sí ojú/ẹ̀gbẹ́ títì.
- ọ̀rá omi,ọ̀rá ìpọ́nkà, ewé irú/ata tí a dà sáàrín ìlú káàkiri.
- ìgbọ̀nsẹ̀ ọmọdé àti ti àgbà tí a yà/dà sínú garawa/ike ìkólẹ̀ láàrin ìlú
- garawa/ike ìkólẹ̀ tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀ láàrin ìlú tí a kò mójú tó rárá
- igbó ṣúúrú ẹ̀yìnkùlé tí a sọ di àkìtàn
(b) Bí akéwì ṣe sọ pé a lè mójú tó àwọn ìdọ̀tí yìí kí wọ́n má baà fa àrùn:
(i) kí á máa ṣe ìpalẹ̀mọ́ ẹ̀gbin/ìdọ̀tí ojú/ẹ̀gbẹ́/inú títì/inú garawa ìdalẹ̀sí lóòrèkóòrè.
(ii) kí ọlọ́pàá máa mú àwọn ará ìlú tí ó bá sọ ọ̀rá/ewé sí ojú/ẹ̀gbẹ́ títì.
(iii) kí ilé kọ̀ọ̀kan ní ṣáláńgá/ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó bójú mu.
(iv) kí ilé kọ̀ọ̀kan ní garawa/gorodóòmù fún ìdalẹ̀sí.
(v) kí a má ṣe sọ igbó ṣúúrú ẹ̀yìnkùlé di àkìtàn.
Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.